Àṣẹ Ọlọ́run kọ́ ni fífẹ́ ju ìyàwó kan lọ-Adewale Ayuba
Fẹ́mi Akínṣọlá
Lẹ́yìn awuyewuye tó gbòde láìpẹ́ yìí, pé gbajúmọ̀ olórin Fuji nnì, Adewale Ayuba, ti kọ ìyàw rẹ̀ sílẹ̀, àti pé òun kọ́ ló ni àwọn ọmọ tí ìyàwó náà bí, Oludasilẹ Bonsue Fuji náà ti ṣe àlàyé kíkún lórií rẹ̀ àti ìhà tó kọ sí fífẹ́ ju ìyàwó kan lọ.
Ninu ifọrọwerọ kan ti Adewale Ayuba ṣe pẹlu iwe iroyin kan lo ti ni ko sohun to jọ pe oun kọ iyawo oun, Azukaego Kwentoh, silẹ. Bẹẹ ni awọn ọmọ mẹfa to bi foun ki i ṣe ọmọ ale rara.
Lasiko ifọrọwerọ naa lo tun sọ iha to kọ si ki ọkunrin fẹ ju iyawo kan lọ.
Nigba to n ṣalaye nipa iha to kọ si igbeyawo, iyawo rẹ ti wọn lo kọ silẹ ati fifẹ ju iyawo kan lọ, olorin Fuji naa sọ pe:
” Lara nnkan ti iroyin ofege nipa igbeyawo mi fi n dun mi gan-an niyẹn. Irọ ni, iroyin naa ko wa lati ọdọ awọn ẹka iroyin ti eeyan le fọkan tan, awọn ti wọn kan fẹ pawo si apo ara wọn lo n gbe e kiri.
“Nigba ti a gbọ iroyin naa, emi ati awọn ẹbi mi kan n rẹrin-in ni. Ọmọ mẹfa ni mo bi, gbogbo eeyan lo mọ Ayuba, awọn ẹbi mi dẹ maa n fi mi yangan ni. Gbogbo wa la mọ pe irọ ni, ko ṣẹlẹ bẹẹ.
“Ọlọrun lo ṣeto igbeyawo, to paṣẹ rẹ. Eewọ ni ki ọkunrin ma niyawo nile. Ọlọrun ṣeto ọkunrin ati obinrin kan, ki i ṣe obinrin meji, ẹyọ kan naa ni. Ọlọrun ko da Adam ati Eefa rẹpẹtẹ.”
Ni afikun alaye rẹ, Adewale Ayuba sọ pe oun gbagbọ pe ilẹkun ibukun kan wa lode ọrun, eyi to maa n ṣi fun ọkunrin to ba ni iyawo kan ṣoṣo.
Ibukun naa maa n wa lati ara iyawo ati awọn ọmọ to ba wa ninu idile gẹgẹ bo ṣe wi.
Koda, o ni awọn eeyan mi-in gbagbọ pe olorin ko le ni idile gidi nitori ọrọ obinrin pupọ, ṣugbọn bi wọn ba fẹyawo lọna to tọ, Ayuba ni ko le ri bẹẹ fun wọn.
O ni oun gbagbọ pe idi niyẹn ti gbogbo nnkan fi n daa foun ati idile oun pẹlu, to jẹ bi awọn ọmọ ba beere ohunkohun ti oun ko ni, oun yoo gba adura, kinni ọhun yoo si jẹ ṣiṣe.
Ayuba ko ṣai sọ pe oun ti bẹrẹ igbesẹ ofin lori akọroyin to kọ ohun ti ko ṣẹlẹ nipa iyawo oun.
O ni ofin yoo ṣe iṣẹ rẹ, ṣugbọn ki ẹnikẹni ma ṣe gba iroyin naa gbọ rara.
Nipa ẹsin Islam to fi silẹ to si di Kristẹni, Adewale Ayuba sọ pe ede Larubawa toun ko gbọ lo fa a.
O ni o rọ oun lọrun lati ka Bibeli, ba Ọlọrun sọrọ lede ti oun gbọ ju ti Kurani lọ.
Ati pe nigba ti oun ri i ka pe Jesu ku foun, iyẹn naa to. O ni ko dẹrun ki ẹnikan too ku fun elomiran, eyi loun ṣe gba a ni Oluwa ati Olugba oun.