Àsà àti ìṣe
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àṣà Yorùbá jẹ́ ọ̀nà tí àwọn ẹ̀yà Yorùbá ń lò láti fi gbé èrò, ìmọ̀, àti ìṣe wọn kalẹ̀ tí ó sì bá àwùjọ wọn mu ọ̀nà tí ó gún gẹ́gẹ́. Tàbí kí á sọ pé Àṣà ni ohun gbogbo tó jẹ mọ́ ìgbé ayé àwọn ènìyàn kan, ní àdúgbò kan, bẹ̀rẹ̀ lórí èrò, èdè, ẹ̀sìn, ètò ìṣèlú, ètò ọrọ̀ ajé, ìsẹ̀dá ohun èlò, ìtàn, òfin, ìṣe, ìrísí, ìhùwàsí, iṣẹ́-ọnà, oúnjẹ, ọ̀nà ìṣe nǹkan, yíyí àyíká tàbí àdúgbò kọ̀ọ̀kan padà. Pàtàkì jùlọ ẹ̀sìn ìbílẹ̀, eré ìbílẹ̀, àti iṣẹ́ ìbílẹ̀. Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n kó’ra jọ pọ̀ ń jẹ́ àṣà. Bí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àṣà àti ìṣe Yorùbá, a ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn ohun tí a ń mú ẹnu bà ni ìhùwàsí àti ìrísí wa láàrín àwùjọ. Nínú ogún-lọ́gọ̀ àwọn àṣà àti ìṣe tí ó ń bẹ nílẹ̀ Yorùbá, ọ̀kan pàtàkì ni’ Àṣà ìkíní nílẹ̀ Yorùbá. Èyí jẹ́ ohun tí gbogbo àwọn ẹ̀yà tí ó kú ní agbáyé fi ma ń ṣàdáyanrí ọmọ káàrọ̀-o kò-jíire bí tòótọ́ ní gbogbo ààyè tí wọ́n bá dé.
Ṣé bẹ́ẹ̀ náà sì tún ni nnkan rí lásìkò yìí? Kó máa ró kì lóókan àyà èmi àti ìwọ.Lábala ìkíni àsìkò yìí, a fi sọrí èèkàn ìlú, ẹlẹ́yinjú àánú tí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ọmọ Orílẹ̀ yìí n bù lá nínú ọrọ̀ t’Édùwà fi dasọ àṣírí bòó.Ìdí nìyí tí mo fi pè é ní Oríkádún.