Yoruba bọ, wọn ni “ọrẹ o ki n y’ọrẹ…” ni eyi to mu ki Alagba Adẹrupọkọ gbera pẹlu agba oserebinrin Toyin Adegbola lati ba Papilolo s’ajọyọ ọjọọbi.
Ayọ Ogunshina ti gbogbo eniyan mọ si Papilolo pe ẹni ọdun mejidinlaadọrun-un (88) loke eepẹ.
Saka lara baba yi tun se.
Mẹta ni awọn baba yii ni nnkan bi ọgbọn ọdun s’ogoji ọdun sẹyin, wọn si gbajọba adẹrinposonu nigba naa. Awọn mẹtẹẹta naa ni Jacob, Aderupoko ati Papilolo yii. Ti wọn ba ti de ori telifisọn, ẹrin arintakiti ni ni igba naa su
gbọn iku ti ọwọ Jacob lawo.










