Olúbàdàn di alága lọ́balọ́ba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́
Fẹ́mi Akínṣọlá
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Sèyí Mákindé ti kéde Olúbàdàn ti ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Rashidi Ládọjà gẹ́gẹ́ alága àwọn lọ́balọ́ba ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Níbi ayẹyẹ kékeré kan tó wáyé ní ilé ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tó wà ní Agodi ìlú Ìbàdàn ni ìkéde náà ti wáyé.
Gómìnà Mákindé ní ipò alága náà yóò máa jẹ́ ohun tí wọ́n ń tò láàárín Olúbàdàn, Aláàfin àti Sọ̀ún ti Ògbómọ̀ṣọ́ láti àsìkò yìí lọ.
Àmọ́ Aláàfin ti ìlú Ọ̀yọ́, Ọba Akeem Owoade kò báwọn kópa níbi ayẹyẹ tí ààfin sì ti fi ìkéde síta pé àwọn kò faramọ́ ìgbésẹ̀ gómìnà náà.
Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ààfin ìlú Ọ̀yọ́, Bode Durojaiye fi síta lọ́jọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Kìíní, ọdún 2026 sọ pé gómìnà Seyi Mákindé kò bá Aláàfin ṣèpàdé ṣáájú kíkéde Olúbàdàn gẹ́gẹ́ bí alága àwọn lọ́balọ́ba ní ìpínlẹ̀ náà.
Durojaiye nínú àtẹ̀jáde náà ní ṣáájú ni àwọn rí àtẹ̀jáde kan pé gómìnà bá Aláàfin, Soun àti Olúbàdàn ṣèpàdé ṣùgbọ́n tí ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ nítorí gómìnà kò bá òun sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀.
“Kò sí ìgbà kankan tí Aláàfin bá Gómìnà Mákindé tàbí àwọn Ọba méjéèjì tí wọ́n dárúkọ ṣe ìpàdé lórí pínpín alága àwọn lọ́balọ́ba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ jẹ láàárín àwọn ọba náà.”
Àtẹ̀jáde náà tẹpẹlẹmọ́ ọ pé Aláàfin àti gbogbo ìlú Ọ̀yọ́ kò fi ọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ lórí ipò wọn lórí ọ̀rọ̀ ọba àti oyè jíjẹ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ nínú àtẹ̀jáde ti wọ́n ti fi ṣáájú ṣọwọ́ sí Gómìnà Mákindé.









