Ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fòǹtẹ̀ lu Ìyànsípò Alága, ọmọ ìgbìmọ̀ tuntun Àjọ OYSIEC

‎Ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fòǹtẹ̀ lu Ìyànsípò Alága, ọmọ ìgbìmọ̀ tuntun Àjọ OYSIEC

Fẹ́mi Akínṣọlá

‎Ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ti fìdí ìyànsípò Ọ̀mọ̀wé Babátúndé Afeez Adéníyì, múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Alága tuntun fún Àjọ elétò ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ (OYSIEC)

‎Bákan náà ni ilé aṣòfin ọ̀hún fìdí ìyànsípò Olóyè Kúnmi Agboọlá, Ọ̀gbẹ́ni Ọláńrewájú Adéòtí Emmanuel, Ọ̀gbẹ́ni Sunday Olúgbémiga Fálànà, Ọnarébù Rẹ̀mí Ayọ̀adé, Ọ̀gbẹ́ni Ọlátúndé Akíntúndé Theophilus, Arábìnrin Adébáyọ̀ Maryam Adépéjú àti Ọ̀gbẹ́ni Babátúndé George Ìgè gẹ́gẹ́ bíi ọmọ ìgbìmọ̀ Àjọ OYSIEC.

‎Nínú ìjókòó ilé tí Adarí ilé, Ọnarébù Adébọ̀ Ògúndoyin tukọ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ ìṣẹ́gun, ni wọ́n ti fìdí ìyànsípò náà múlẹ̀.

‎Ìgbésẹ̀ yìí wáyé lẹ́yìn tí ilé tẹ́wọ́ gba àbọ̀ àti àbá ìgbìmọ̀ tẹ̀kótó ilé aṣòfin tó ń mójútó àwọn ojúṣe pàtàkì, lórí àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe fún àwọn onítọ̀hún tí Gómìnà Ṣèyí Mákindé, fi orúkọ wọn ránhúnṣẹ́.

‎Nígbà tí ó ń ka àbọ̀ ọ̀hún, Alága ìgbìmọ̀ tẹ̀kótó náà, tó tún jẹ́ igbákejì adarí ilé aṣọ̀fin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọnarébù Abíọ́dún Fádèyí, jẹ́ kó di mímọ̀ pé Alága àti àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ OYSIEC, fi ìdáhùn tó yẹ, tó sì tẹ́ àwọn lọ́rùn, sí gbogbo ìbéèrè tí àwọn tàkòtò sí wọn àti wípé wọ́n fi hàn pé àwọn yẹ fún ipò ọ̀hún.

‎Nígbà tó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀, kété lẹ́yìn ìfìdìmúlẹ̀ ìyànsípò rẹ̀, Alága tuntun Àjọ OYSIEC, Ọ̀mọ̀wé Babátúndé Afeez Adéníyì, sọ pé lọ́gba tí wọ́n bá ṣe ìbúra fún àwọn, ni àwọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe iṣẹ́ ìríjú tí ìlú fẹ́ fi rán àwọn.

‎Ní ìtẹ̀sìwájú ọ̀rọ̀ ọ̀mọ̀wé Babátúndé, ó ṣèlérí pé nígbà tí ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ yóò bá fi wáyé ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lábẹ́ àmójútó òun, àwọn yóò ṣe ní ìbámu pẹ̀lú àlàkalẹ̀ òfin ìdìbò.

‎Alága Àjọ OYSIEC, tún fi àkókò náà dúpẹ́ lọ́wọ́ ọ Gómìnà Ṣèyí Mákindé, fún bó ṣe fi ọkàn tán òun fún ipò ọ̀hún, pẹ̀lú ẹ̀jẹ́ pé òun kò ní já Gómìnà àti àwọn ará ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kulẹ̀.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here