Ìkéde pàjáwìrì lẹ́kà ààbò tí Tinubu ṣe àti bó ṣe kàn aráàlù
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àná Ọjọ́rú ni Ààrẹ Bola Tinubu kéde òfin pàjáwìrí ní ẹ̀ka ètò àbò Nàìjíríà, paàpàá láwọn ìlú tí ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé ti di gbọnmọgbọnmọ lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí.
Aarẹ tun paṣẹ ki wọn gba nnkan bii ẹgbẹrun lọna aadọta eeyan siṣẹ ọlọpaa ati ileeṣẹ ologun lati le koju eto abo to mẹhe.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ileeṣẹ ọlọpaa gbọdọ gba oṣiṣẹ bii ẹgbẹrun lọna aadọta lati kun awọn ọlọpaa 370,000 to wa nilẹ lọwọ.
Onimọ nipa eto aabo naa, Akin Adeyi wa salaye koko ohun to maa sẹlẹ lasiko yii ti ijọba apapọ kede igbesẹ pajawiri lẹka eso aabo.
O ni ijọba ni ojuṣe lati ṣalaye ohun to n ṣẹlẹ fun araalu ki araalu naa si fọwọsowọpọ pẹlu ijọba.
Awọn koko to mẹnuba pe yoo sẹlẹ ree:
Naijiria yoo gbe gbogbo ofin to rọ mọ eto abo ti ṣẹgbẹ kan, ki awọn agbofinro le ṣe iṣẹ wọn bo ṣe yẹ lai si idiwọ kankan fun wọn.
Ofin pajawiri ni wọn yoo maa lo lakoko yii lawọn agbegbe ti ọrọ kan.
Awọn agbofinro le gbe irufẹ igbesẹ bẹẹ lai kọkọ duro de aṣẹ lakoko naa. Boya tẹlẹtẹlẹ, o yẹ ka duro de aṣẹ kan lati ibi kan ki a to le gbe igbese lati pinwọ iwa ibi kan, ko ni si bẹẹ mọ,
Ẹni to ba wa lagbegbe kan lasiko iṣẹlẹ ibi ba n waye le gbe igbesẹ lati yanju ọrọ naa lai kii ṣe pe o kọkọ beere lọwọ ẹnikẹni, ti ẹnikẹni ko si ni beere lọwọ rẹ pe ‘kilode ti o fi ṣe bẹẹ.’ Kii ṣe pe ki ọgagun kan ṣẹṣẹ maa duro de aṣẹ lati oke… tabi ko maa sọ pe wọn ti ni ki a ma yinbọn si wọn mọ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Awọn irin gberegbere kan ko ni si mọ.
Ko ni nilo ki wọn ṣẹṣẹ kede konileogbe mọ, agbofinro kan le da eeyan duro ko si sọ pe ‘oya, maa lọ inu ile rẹ’ lai ṣe pe niṣe lo tẹ ẹtọ araalu naa mọlẹ lati rin lasiko to ba wu u.”
Ikede Aarẹ naa ti gbe ẹtọ araalu nipa ọrọ abo si ẹgbẹ kan ati pe gbogbo ẹka ileeṣẹ agbofinro ni Naijiria lo le ṣiṣẹ ara wọn lai si idiwọ kankan.
Ọlọpaa le ṣiṣẹ ṣọja, ti ṣọja yoo le ṣiṣẹ ọlọpaa; bẹẹ ni DSS le ṣiṣẹ NSCDC, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Nigba to n sọrọ lori igbesẹ Aarẹ lati gba nnkan bii ẹgbẹrun lọna aadọta eeyan si ileeṣẹ ọlọpaa, Adeyi ni imọ ẹrọ ni a nilo, kii afikun ọlọpaa.
O ni “Ko ni nnkankan lati ṣe pẹlu didaabo bo araalu bi ko ṣe ọrọ oṣelu pe ‘ti a ba fun awọn ọmọ wọn nisẹ diẹ boya wọn maa tun dakẹ.’
“Ọrọ ọlọpaa ati eto abo laye ode oni kii ṣe nipa ki ọlọpaa pọ lapọju, bikoṣe nipa lilo imọ ẹrọ.
“Asiko ti awọn orilẹede ti wọn mọ nnkan ti wọn n ṣe n sọ pe kii ṣe nipa ọpọ ero nileeṣẹ eto abo lawa ṣẹṣẹ n sọ pe a gbọdọ gba ọpọ ero siṣẹ ọlọpaa.
“Eeyan meji pere ninu yara kan le ṣe iṣẹ ẹgbẹgbẹrun eeyan pẹlu ẹrọ ‘drone’ to n fo loju ofurufu.”
O ni kii ṣe nipa gbigba ọpọ ero siṣẹ ọlọpaa ni eto abo yoo fi dara amọ nipa lilo imọ ẹrọ igbalode fun eto abo.
Onimọ eto abo naa sọ pe araalu gbọdọ maa sin ijọba atawọn agbofinro ni gbẹrẹ ipakọ paapaa lasiko ti ọdun n sunmọle yii.
Adeyi ni wọn gbọdọ maa bun ọlọpaa gbọ ni gbogbo igba ti wọn ba kofiri nnkan tabi eeyan ti ko yẹ layika wọn.
Lẹyin naa lo mẹnuba ọrọ awọn ọlọkada to n lo iboju lasiko yii.
O ni ko tọ fun ọlọkada lati maa lo iboju lati ṣiṣẹ nitori iru wọn le gbe eeyan lọ ti ẹnikẹni ko si ni mọ irufẹ ẹni to wa labẹ iboju ọhun.
O pari ọrọ rẹ pe oju ni alakan fi n ṣọri pe gbogbo araalu gbọdọ maa funra ki wọn si ṣọra fun ibi ti ọpọ ero ba pọju si lasiko pọpọṣinṣin ọdun nitori asiko yii gan ni awọn kọlọrọsi ẹda maa n ṣọṣẹ.









