Èyí ni bí ọwọ́ ọlọ́pàá ṣe tẹ afurasí ikú òṣìṣẹ́ FRSC àti ọmọ rẹ̀

Èyí ni bí ọwọ́ ọlọ́pàá ṣe tẹ afurasí ikú òṣìṣẹ́ FRSC àti ọmọ rẹ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ Ghana ti kede pe ọwọ awọn ti tẹ afurasi apaayan kan, Victor Benjamin Fajemirokun, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, tí wọ́n fẹsun kan pé wọn lọwọ ninu iku oṣiṣẹ FRSC ti wọn ji gbe niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.

Ọga ọlọpaa kan nilẹ Ghana lo fi iroyin naa lede ninu fọnran kan to tẹ akọ̀ròyìn lọwọ lálẹ́ ọjọ́ ÀìkÚ tó kọjá.

Nínú alaye rẹ, ọ̀gá ọlọ́pàá náà ṣàlàyé bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe waye.

”Mo fẹ fi to o yin leti nipa ọmọ ilẹ Naijiria kan ti a fura si pe o pa obinrin kan ati ọmọ rẹ lorileede Naijiria, to si sa wa si Ghana lati maṣe jẹ ki ọwọ ọlọpaa tẹ ẹ ni Naijiria.

”Victor Benjamin Fajemirokun, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn ni ọwọ tẹ lori fọnran kan to n lọ kaakiri ori ayelujara, nibi ti wọn ti fẹsun kan an wi pe o ṣeku pa oṣiṣẹbinrin ti ajọ Road Safety, iyẹn FRSC, ati ọmọ rẹ ni Abẹokuta.

”Afurasi naa ni ileeṣẹ ọlọpaa Naijijria n wa, ṣugbọn to sa wa si Ghana lati farapamọ lọdọ ọrẹ rẹ kan.

Nigba ti a gbọ ibi ti afurasi naa farapamọ si, awọn ọlọpaa sare lọ sibẹ lati mú.

O si ti wa lahamọ wa bayii, pẹlu bi igbesẹ ṣe n lọ lati fa a le ọlọpaa Naijiria lọwọ,” iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Ghana lo ṣalaye bẹẹ.
Ọgbẹni Jimoh Lasisi, to jẹ ọkọ Oluwamayokun, oṣiṣẹ FRSC ti wọn pa nipinlẹ Osun ti bá BBC News Yorùbá sọrọ nípa ikú aya rẹ náà.

Lasisi ni ibanujẹ nla lo jẹ fún òun wi pe awọn amookunṣeka ṣeku pa iyawo oun, ati ọmọ obinrin kan ṣoṣo tI òun bi nigbesi aye oun.

Lasisi ni bo tilẹ jẹ pe ko tii to akoko lati sọrọ, sibẹ, oun ko nii ṣai sọ diẹ lati le jẹ ki awọn eeyan mọ okodoro ọrọ èyí to yatọ si ohun ti awọn eeyan n gbe kaakiri ori ayelujara.

”Mi o tii ro pe asiko ree fun mi lati sọrọ, nitori pe iwadii ṣi n lọwọ.

Ẹnu mi nikan naa lẹ ti le gbọ okodoro, ṣugbọn lọwọlọwọ bayii, mo ni lati mọ riri gbogbo ẹyin akọroyin patapata ati awọn to n ba mi kẹdun,”

Ọgbẹni Jimoh sọ bẹẹ fun akọroyin.

Baale ile naa sọ pe nigba to to asiko lati ba iyawo ati ọmọ oun sọrọ, ṣugbọn toun ko gburo wọn, lo jẹ ki ara fu oun, toun si ranṣẹ sawọn eeyan lati ṣewadi ibi ti wọn wa.

”Emi ni mo fun awọn ọlọpaa nibi ti Victor n gbe niluu Ileṣa ati Osogbo, mo si ni gbogbo iroyin naa lọwọ.

A ti ri oku Sewa, niṣe lo pa oun naa.

Awa araalu nilo ọpọ nnkan lati ṣe, lati maa fi daabo bo ara wa.

Ọmọbinrin kan ṣoṣo ti mo ni niyẹn.”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here