Tinubu s̩èdárò ìpapòdà Bayo̩ Osiyemi

Tinubu s̩èdárò ìpapòdà Bayo̩ Osiyemi

Yínká Àlàbí

Ààrẹ Bola Tinubu ti fi e̩mi ibanike̩dun rẹ̀ han nípa ikú Ọmọ-Ọba Bayo Osiyemi, onkọ̀wé, akọ̀ròyìn àti ọ̀rẹ́ pípẹ́ rẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí ìkéde tí olùkọ́ròyìn Ààrẹ, Bayo Onanuga, salaye faye, Osiyemi jẹ́ olórí gbogi ninu APC ní Èkó, ó sì ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Akọ̀wé Ìròyìn fún Gómìnà Lateef Jakande ní àsìkò rẹ̀.
Ó kú ní Èkó ní ọjọ́ Mọ́ńdé ni e̩ni ọdún marundinlo̩go̩rin (75).
Tinubu pè é ní olóṣèlú, olókìkí, ọ̀rẹ́ tí ó se e gbẹ́kẹ̀ lé, àti olórí ti ko se e fo̩wo̩ ro̩ se̩yin ni ilu Mushin. Ó tún jẹ́ Ààrẹ ìgbìmọ̀ ìjọba agbègbè Mushin nígbà kan.
Tinubu ranti iṣẹ́ rere àti ìtẹ́wọ́gbà tí Osiyemi fi sí ìgbèlárugẹ Èkó, pàápàá jùlọ nípa iṣejọba àti àjọṣe awo̩n oloye, tí Gómìnà Babajide Sanwo-Olu fi yàn án sípò olùrànlọ́wọ́ pàtàkì ní ọ̀rọ̀ oye jije̩.
Ó bá ẹbí, àwọn ọ̀rẹ́ àti ojulumo̩ ke̩dun, ó sì gbàdúrà kí Ọlọ́run fún un ní ìsinmi àìnípẹ̀kun.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here