Small Doctor sàbè̩wò sí Obasa
Yínká Àlàbí
Olólùfé orin Nigerian, Adekunle Temitope tí a mọ̀ sí Small Doctor, pada sí agbègbè rẹ̀ ní Agege ní ọjọ́ Ajé, níbi tí ó lọ bá Alaga Ìjọba ibile̩ Agege, Ganiyu Obasa.
Small Doctor ni oun àti Alaga náà fẹ́ ṣiṣẹ́ pọ̀. O ni gnogno eniyan lo kuku mo̩ pe ọmọ bíbí Agege ni oun, eyi si je̩ ki oun wá sí ọ́fíìsì Obasa pẹ̀lú awo̩n ẹgbẹ́ oun.
Ìbẹ̀wò náà dá lórí bí wọ́n ṣe lè mú ẹ̀dá àti ìrìnàjò lọ síwájú ní Agege, kí wọ́n sì lo amúlò rẹ̀ láti mú àwọn ọdọ ṣiṣẹ́.
Obasa sọ pé: “Àwọn ọdọ máa n fọwọ́sowọpọ̀ púpọ̀ pẹ̀lú eré ìbánisọ̀rọ̀ àti orin. A lè kó wọn jọ nípasẹ̀ ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn akíkanjú ilé-iṣẹ́ eré bí Small Doctor. Ìbẹ̀wò yìí bójú mu, àwọn ọdọ yóò sì rí èrè rẹ̀ laipẹ́.”
O fi kun un gbogno aye lo mo̩ pe Aja iwoyi lo mo̩ Ehoro iwoyi le. O ni lati wo̩n jo̩ maa ro̩run fun awo̩n nitori pe sawawu kan naa ni awo̩n.
Small Doctor tun salaye pe a ko gbo̩do̩ gbagbe pe “o̩wo̩ to ba dile̩ ni Esu n be̩ nis̩e̩”.









