Is̩é̩ pò̩ fún akó̩nimò̩ó̩gbá Super Eagles – Okocha
Yínká Àlàbí
Agbábọ̀ọ̀lù te̩le̩ rí fun iko̩ Super Eagles, Austin Okocha, ti kéde pé ohun tí ẹgbẹ́ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà gbọ́dọ̀ tún ṣe kí wọ́n lè ṣàṣeyọrí ní AFCON 2025 ni àìle duro sori o̩wo̩ kan, nínú eré wọ́n.
Ó sọ pé ìkọ̀ ẹgbẹ́ náà ṣi ń bà a lórí ìkùnà tí wọ́n ṣe ní World Cup 2026, níbi tí wọ́n ti ṣe idije mẹ́wàá, wọ́n ṣẹ́gun mẹ́rin, wọ́n ta o̩mi márùn-ún, wọ́n sì padanu idije kan. Wo̩n padanu idije pe̩lu orileede Benin. O̩mi ti wo̩n gba pe̩lu orileede Lesotho àti Zimbabwe lo mú kí ọ̀pọ̀ o̩mo̩ Naijiria ko o̩kan kuro lara wo̩n.
Nígbà tí wọ́n parí pe̩lu ipo keji lẹ́yìn South Africa, wọ́n padanu tikẹ́ẹ̀tì taara sí World Cup.
Iko̩ Super Eagles tun padanu anfani keji to tun yo̩ju fun awo̩n to ba fidi re̩mi, eyi ni wo̩n n pe ni “play-off”.
Ní ti AFCON 2025 ní Morocco, Super Eagles wà ní ẹgbẹ́ kan pẹ̀lú Tunisia, Uganda àti Tanzania, wọ́n sì ní ireti pé Eric Chelle yóò ko wo̩n de ile̩ ileri.









