Àṣà àti ìṣe
Fìlà dídé,gèlè wíwé, àrokò tí a fi pa sí àwùjọ
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àṣà Yorùbá jẹ́ ọ̀nà tí àwọn ẹ̀yà Yorùbá ń lò láti fi gbé èrò, ìmọ̀, àti ìṣe wọn kalẹ̀ tí ó sì bá àwùjọ wọn mú ní ọ́nà tí ó gun gẹ́gẹ́. Tàbí kí á sọ pé Àṣà ni ohun gbogbo tó jẹ mọ́ ìgbé ayé àwọn ènìyàn kan, ní àdúgbò kan, bẹ̀rẹ̀ lórí èrò, èdè, ẹ̀sìn, ètò ìṣèlú, ètò ọrọ̀ ajé, ìsẹ̀dá ohun èlò, ìtàn, òfin, ìṣe, ìrísí, ìhùwàsí, iṣẹ́-ọnà, oúnjẹ, ọ̀nà ìṣe nǹkan, yíyí àyíká tàbí àdúgbò kọ̀ọ̀kan padà. Pàtàkì jùlọ ẹ̀sìn ìbílẹ̀, eré ìbílẹ̀, àti iṣẹ́ ìbílẹ̀. Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n kó ara jọ pọ̀ tí wọ́n ń jẹ́ àṣà.
Bí a bá sọ̀rọ̀ nípa àṣà àti ìṣe Yorùbá, nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ lórí nǹkan kan, àwọn ohun tí à ń mú enu bà ni ìhùwàsí àti ìrísí wa láàrín àwùjọ. Nínú ogún-lọ́gọ̀ àwọn àṣà àti ìṣe tí ó ń bẹ nílẹ̀ Yorùbá, ọ̀kan pàtàkì ni’ Àṣà aṣọ wíwọ̀ jẹ́ lábẹ́ ìmúra gẹ́gẹ́ bí ọmọ Yorùbá. Ó wà lára ohun tí gbogbo àwọn ẹ̀yà tí ó kú ní agbáyé fi máa ń ṣàdáyanrí ọmọ káàrọ̀-oò-jíire ní gbogbo ayé tí wọ́n bá dé.
Àgbéyẹ̀wò fìlà àtì gèlè lafẹ́ mẹ́nubà, níbẹ̀ la ó ti
sọ ohun mẹ́ta tí oríṣi gèlè wíwé ń sọ àti ohun tí ọ̀nà márùn-ún tí a ń gbà dé fìlà ń wí, ẹ má a fi ọkàn kà á nìṣó.
Ní ilẹ̀ Yorùbá, onírúurú ọ̀nà mẹ́ta ni àwọn obìnrin ń gbà wé gèlè.
Wọn máa ń we gele si iwaju, ẹyin tàbí ẹgbẹ.
Ìkọ̀ọ̀kan ọna mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí wọn ń gba we gèlè yìí sí lo ni ìtumọ̀ tiwọn.
Bákan náà ni fìlà dìde, ọ̀nà márùn-ún ni àwọn ọkùnrin ń gba de fila wọn.
Wọ́n le dé fìlà sì ọwọ́ iwájú, ẹ̀yìn, ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún tàbí òsì tàbí kí wọ́n na fìlà náà gogoro sì òkè
Ìkọ̀ọ̀kan ọ̀nà márààrún tí wọn ń gba de fìlà yìí sí lo ni ìtumọ̀ tiwọn.
wà ṣe àkójọpọ̀ àwọn ọ̀nà tí obìnrin ń gba wé gèlè àti ọ̀nà márùn-ún tí ọkùnrin ń gbà gẹ fìlà pẹ̀lú ohun tí àwọn ìlànà náà túmọ̀ sí.
Ìtumọ̀ kí obìnrin dé gèlè sí iwájú, ẹyin àti ẹgbẹ́?
Ìgbàgbọ́ Yoruba ni pé bí àwọn obinrin to wa nile ọkọ lọ máa ń kọ ojú gele wọn sì ọwọ́ iwájú.
Ìdí ni pé tiwọn ni ayé ń gbọ́.
Bákan náà, wọn gbagbọ pé àwọn obìnrin tó ti di arúgbó lọ máa ń we gele si ọwọ́ ẹyin.
Èyí túmọ̀ sí pé ọjọ́ wọn tí di alẹ.
Àmọ́ ọmọge to ń wá ọkọ lọ máa ń kọ ojú gele rẹ sì ọwọ́ ẹgbẹ́.
Ìtumọ̀ ọna márùn-ún tí àwọn ọkùnrin ń gba de fila
Bí ọkùnrin bá gẹ fìlà sì ọwọ́ iwájú, ó túmọ̀ sí pé ayé dun jẹ ju ìyá lọ, sì ń bẹ lọ́wọ́ iwájú.
Bí wọn ba gẹ fìlà sì ọwọ́ àlàáfíà, ó túmọ̀ sí pé ọkùnrin bẹẹ tí ní ìyàwó nílẹ̀.
Bí ọkùnrin bá gẹ fìlà sì apá ọ̀tún, ó túmọ̀ sí pé apọn ni, kò ti ní ìyàwó nílẹ̀, ó sì ń wá ìyàwó.
Bí ọkùnrin bá sì gẹ fìlà sì ọwọ́ ẹyin, ó túmọ̀ sí pé kò sí ohun tuntun lábẹ́ ọrùn mọ.
Àmọ́ tí ọkùnrin kan kan ṣe fìlà rẹ gogoro, ó túmọ̀ sí pé ó ń sọ fún àwọn èèyàn pé ẹni ńlá ni òun.
Ibo wá ní ẹyin ń kọ ojú fìlà àbí gele yín sí?









