A ò gbọ́ ohunkóhun látọ̀dọ̀ àwọn tó jí akẹ́kọ̀ọ́ 315 gbé ní ilé ẹ̀kọ́ St Mary’s – CAN

A ò gbọ́ ohunkóhun látọ̀dọ̀ àwọn tó jí akẹ́kọ̀ọ́ 315 gbé ní ilé ẹ̀kọ́ St Mary’s – CAN

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ẹgbẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi ní Nàìjíríà, Christian Association of Nigeria (CAN) tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Niger ti jiyàn ìròyìn kan tó gbòde wí pé àwọn agbébọn tó jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ 315 gbé ní ilé ẹ̀kọ́ St. Mary’s Catholic Primary and Secondary Schools, Papiri, ìpínlẹ̀ Niger ń bèèrè fún bílíọ̀nù mẹ́ta náírà gẹ́gẹ́ bí owó ìtúsílẹ̀.

Alága CAN ìpínlẹ̀ Niger, Ẹni ọ̀wọ̀ Bulus Dauwa Yohanna ló fi ìròyìn náà léde lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.

Yohanna ní àwọn agbébọn náà kò ì tíì kan sí ẹnikẹ́ni lórí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn olùkọ́ tí wọ́n jí gbé náà.

Ó ní lóòótọ́ ni onírúurú ìròyìn ti gbilẹ̀ lórí ayélujára èyí ló sì ṣokùnfà tí àwọn fi ń gbé àtẹ̀jáde síta lóòrèkóòrè.
Bákan náà ló fi kun pé iye èèyàn tí àwọn agbébọn náà jí gbé nílé ẹ̀kọ́ ọ̀hún jẹ́ 315 – àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 303, àwọn olùkọ́ 12 – lòdì sí iye èèyàn 227 tí wọ́n ti kọ́kọ́ kéde pé àwọn agbébọn náà gbé.

Bíṣọ́ọ̀bù náà sọ pé lẹ́yìn tí àwọn kúrò ní Papiri, tí àwọn bẹ̀rẹ̀ sí ní kàn sáwọn èèyàn ni àwọn ri pé gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí àwọn rò wí pé wọ́n móríbọ́ ló jẹ́ pé wọ́n wà ní àkàtà àwọn ajínigbé náà.

Ó ní àwọn ṣàwárí rẹ̀ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méjìléláàádọ́rùn-ún (88) míì ṣì wà ní àkàtà àwọn ajínigbé náà.

Lórí ọ̀rọ̀ pé ìjọba ti ṣèkìlọ̀ fáwọn ilé ẹ̀kọ́ lórí ìkọlù àwọn agbébọn náà, Yohanna ní àwọn kò gba ìwé ìkìlọ̀ kankan yálà láti ọ̀dọ̀ ìjọba tàbí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here