Ìyàwó parọ́ mọ́ ọkọ pé ó bà ọmọ àwọn obínrin lò pọ̀
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé wọ́n ní olóòtọ́ kìí kú sí ipò ìkà.
Òrọ̀ ti bẹ́yìn yọ fún ìyàwó ilé kan ní ìpínlẹ̀ Enugu, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Chisom, tó fi ẹ̀sùn kan ọkọ rẹ̀ pé ó bá àwọn ọmọ àwọn obìnrin méjì lò pọ̀, tí ẹ̀sùn ọ̀hún sì padà jẹ́ irọ́ lásán.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Enugu, SP Daniel Ndukwe, ṣalaye pe Chisom fi ẹsun ifipaba awọn ọmọ ti ọjọ ori wọn jẹ marun-un ati mẹta lo pọ, kan baba wọn, Ozioma Okonkwo.
Eyi lo fa a ti awọn ọlọpaa fi mu baba naa si ahamọ, bo tilẹ jẹ pe o n sunkun kikoro ninu fidio ti wọn ti mu un pẹlu ṣẹkẹsẹkẹ lọwọ, o ni oun ko ṣe ohun ti iyawo oun sọ fun ọlọpaa.
Awọn ọlọpaa bẹrẹ iwadii lẹyin ti wọn ti gbe ọkọ naa ju si ahamọ, iwadii naa lo si jẹ ki wọn mọ pe ko si ẹri kan to fẹsẹ mulẹ pe ẹni to wa lahamọ naa ṣẹ loootọ.
Lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹwaa ọdun 2025 ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Enugu, gba ifisun lati ọdọ Chisom, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn (29).
O ṣalaye fun wọn pe ọkọ toun bi awọn ọmọ mẹta fun (ọkunrin kan, obinrin meji) n ba awọn ọmọbinrin naa ti ọjọ ori wọn ko ju marun-un ati mẹta lo, ṣe iṣekuṣe.
Obinrin naa fi kun un pe ọkọ oun ni ko jẹ koun tu aṣiri naa tipẹ, nitori o leri lati pa oun boun ba sọ fun ẹnikẹni.
Eyi ni awọn ọlọpaa bẹrẹ iwadii lorii rẹ, lẹyin ti wọn ti gbe ọkọ ju si ahamọ.
Iwadii pada fidi ẹ mulẹ, pe akoba lasan ni ẹsun ti Chisom n ka si ọkọ rẹ lẹsẹ.
Alukoro ọlọpaa Enugu sọ pe iwadii awọn fi han, pe 2024 si 2025 ti Chisom fẹsun iṣekuṣe naa kan ọkọ, lo ti funra rẹ ko awọn ọmọdebinrin ọhun lọ si ipinlẹ Imo, lati Enugu.
Awọn ọmọ ko tilẹ si lọdọ baba wọn lasiko ti iya n fẹsun naa kan baba.
Bakan naa, akọbi wọn to jẹ ọkunrin, ọmọ ọdun meje, ṣalaye fun awọn ọlọpaa pe iya awọn lo kọ oun ati awọn aburo oun obinrin lati purọ mọ baba awọn.
Lẹyin ti iwadii ọlọpaa ti fi han pe irọ ni ẹsun ti Chisom fi kan ọkọ rẹ, wọn fi ọwọ ofin gbe oun naa.
Wọn gbe e lọ sile ẹjọ majisreeti ipinlẹ Enugu, lori ẹsun meji to rọ mọ ibanilorukọjẹ ati sisọ ohun ti ko ri bẹẹ.
Laaarin asiko naa, Chisom gbiyanju lati fi opin si ẹjọ to n lọ lọwọ, ati iwadii ọlọpaa, ṣugbọn wọn ko gba fun un.
Kootu fi aaye beeli silẹ fun un, wọn si sun igbẹjọ siwaju.
Bi ẹnikẹni ba jẹbi ẹsun ibanilorukọjẹ ni Naijiria, ijiya rẹ ni ẹwọn ọdun kan tabi meji pẹlu owo itanran.
Ẹnikẹni ba si to eke lorilẹede yii, ẹwọn ọdun mẹrinla gbako ni ijiya rẹ.









