Tinubu pa ìrìnàjò tì nítorí ààbò ìlú
Yínká Àlàbí
Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti fagilé irin-ajo rẹ̀ sí G20 Summit ní South Africa àti AU-EU Summit ní Angola, kí ó lè foju to eto ààbò nípa awọn ọmọbìnrin ile-iwe tí wo̩n ji ní Kebbi àti àwakọ̀ ọdaran tó kọlu àwọn oníjọsìn ní Eruku, Kwara State.
Lẹ́yìn ìbéèrè Gómìnà Kwara, Ààrẹ Tinubu paṣẹ pé kí ogunlo̩go̩ ọlọ́pàá àti ọmọ ogun bale̩ sí Eruku àti gbogbo ijo̩ba ibile̩ Ekiti.
Ó tún ní kí ọlọ́pàá tẹ̀ lé àwọn ajinigbé tí wọ́n kọlu àwọn oníjọsìn ní ilé ìjọ Christ Apostolic Church, Eruku.
Aare̩ Tinubu ti digba dagbo̩n láti lọ sí G20 Summit lọ́jọ́ tí wọ́n yàn, ṣùgbọ́n ó dá irin-ajo dúró torí ìṣòro ààbò tó ṣẹlẹ̀ ní Kebbi àti Kwara.
Ó ń dúró de ìròyìn látọ̀dọ̀ Igbakeji Ààrẹ Kashim Shettima to ran lọ sí Kebbi, àti látọ̀dọ̀ o̩lo̩paa inu ati tode nípa iṣẹlẹ̀ ipinle̩ Kwara náà.
Ààrẹ Tinubu tún paṣẹ pé kí àwọn agbofinro ṣe gbogbo ohun tí ó ṣeé ṣe láti gba awọn ọmọbinrin me̩rinlelogun tí awo̩n ajinigbé ji ní Kebbi kí wọ́n sì rii pe awo̩n ko wo̩n de ni pipe.









