Òógùn ojú mi ni mò ń je̩ – O̩ko̩ya

Òógùn ojú mi ni mò ń je̩ – O̩ko̩ya

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà sọ pé bí ògún ẹni bá dánilójú, ṣe ni a fií gbá àyà ẹni.Èyí ló mú kí Raheem Okoya, ọ̀kan lára àwọn ọmọ gbajúmọ̀ oníṣòwò nnì tó ni iléeṣẹ́ Eleganza Group, Olóyè Rasaq Okoya sọ pé gbogbo owó àti ọrọ̀ tí òun kó jọ ló jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ òun.

Okoya ní lòdì sí ìgbàgbọ́ àwọn èèyàn pé ọlá bàbá òun ni òun fi ń mí, ó ní iṣẹ́ ọwọ́ òun ni ọlà tí òun kó jọ.

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tí Raheem ṣe pẹ̀lú iléeṣẹ́ Wazobia Max Television ló ti sọ̀rọ̀ náà tí fídíò rẹ̀ sì ti gba orí ayélujára.

Ó ní gbogbo owó tó wà ní akoto báǹkì òun lónìí òógùn òun àti pé òun ní ìfarajìn sí dídádúró àti níní ọrọ̀ tó jẹ́ ti ara rẹ̀ láì gbé ara lé ẹbí.

Ó fi ìgboyà sọ pé “gbogbo tọ́rọ́ tó wà ní báǹkì mi lónìí ló jẹ́ ti iṣẹ́ tí mò ń ṣe, òógùn mi.”

Raheem fi kun pé pẹ̀lú gbogbo àwọn nǹkan tí òun ti kó jọ yìí, òun kò ì tíì dé ibi tí òun fẹ́ láyé àmọ́ tí òun ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ibi tí òun wà.

“Kìí ṣe pé mo ti dé ibi tí mo fẹ́ láyé àmọ́ t imo bá fẹ́ jẹun, ohun tó wù mí nim ò ń jẹ.”
Ní oṣù Kìíní ọdún 2025 ni òkíkí Rahaeem Okoya kàn lórí ayélujára.

Èyí kò ṣẹ̀yìn fídíò kan tí Raheem àti Wahab fi sórí ayélujára léyìí tó ṣàfihàn ọlọ́pàá kan tó báwọn gbé owó dání, tí wọ́n sì ń ná owó náà níbi òde àríyá kan.

Tí àwọn èèyàn sì ń bèèrè pé ta ni àwọn ọmọkùnrin náà tí ọlọ́pàá ń bá kó owó dání.

Raheem Okoya nínú fídíò kan sọ pé òun ni adarí iléeṣẹ́ Eleganza Group.

Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ tí ìyàwó kékeré Rasaq Okoya, Shade Okoya bí fún-un.

Ó ṣeéṣe kí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ òde òní má mọ ẹni tí Rasaq Okoya títí di ìgbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣàfihàn ara wọn nínú fídíò tí wọ́n ti kó ọ̀bítíbitì owó dání náà.

Ọ̀pọ̀ ìbéèrè tó gba ẹnu àwọn èèyàn lórí ayélujára lẹ́yìn tí fídíò náà gbòde ni pé kí ló fà á tí ọlọ́pàá fi máa gbé owó dání fáwọn ọmọ ọ̀hún.

Awuyewuye náà ṣokùnfà kí agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá nígbà náà, Muyiwa Adejobi fi àtẹ̀jáde síta pé àwọn ti fi ọlọ́pàá náà sí àhámọ́.
Ògbóǹtarigì oníṣòwò, tó tún jẹ́ olùdásílẹ̀ iléeṣẹ́ Eleganza Group of Companies ni Rasaq Okoya.

Ti a ba n sọrọ nipa onisowo to lamilaka lorilẹede Naijiria, ọkan gboogi ni Razaq Okoya.

O jẹ alaga ati oludari ileeṣẹ Eleganza to wa niluu Eko.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn tó dàgbà sí Nàìjíríà ní ìbẹ̀rẹ̀ 1990 ni yóò rántí dáadáa nípa àwọn ohun èlò ilé bíi àga oníke, ike ìpọnmi tàbí kúlà tó jẹ́ ti iléeṣẹ́ Eleganza.

Ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni Okoya da iléeṣẹ́ náà sílẹ̀, tó sì ní ẹ̀ka káàkiri.

Wọn bi Okoya si ilu Eko ni ọjọ kejila oṣu kinni ọdun 1940 ni ile Tiamiyu Ayinde ati Idatu Okoya.

Ọdún 2025 yìí ni Okoya máa pé ẹni ọdún márùndínláàádọ́rùn-ún lókè èèpẹ̀, tó sì jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Eko.

O lọ si ile ẹkọ alakobẹrẹ ni Absar-un-deen ni Oke Popo ni Isalẹ Eko.

O bẹrẹ lati kọ iṣẹ ransọransọ pẹlu Baba rẹ, to si ti mọ nipa iṣẹ naa ko to pari ile ẹkọ alakọbẹrẹ.

Okoya ni ọpọ iyawo, to si bi ọpọ ọmọ.

Ní 1999 ni ó fẹ́ Shade Okoya tó jẹ́ ìyàwó rẹ̀ tó kéré jùlọ, òun sì ni ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ mọ̀-ọ́n.