Ìmísí fè̩hìn àwo̩n ake̩gbé̩ re̩ nalè̩ lórí ètò BBNaija 2025

Ìmísí fè̩hìn àwo̩n ake̩gbé̩ re̩ nalè̩ lórí ètò BBNaija 2025

Mary Fágbohùn

Omole lori eto BBNaija, Imisi, ti gbade bii eni jawe olubori ninu abala ti odun 2025 lori eto naa.

Imisi fi eyin awon omole meji miran ti won jo de ipele asekagba nale, o si gba ebun owo milionu lona aadojo naira (N150m) leyin ojo mokanlelaadorin ninu ile.

Abala “10/10” eto naa bere ni Ojo Abameta Osu Keje 2025, to safihan ifigagbaga laarin omole mokandinlogbon — obinrin marundinlogun ati okunrin merinla.

Amo sa ni ipele asekagba, omole mesan-an pere lo wa nibe: Dede, Imisi, Isabella, Jason Jae, Kaybobo, Kola, Koyin, Mensan ati Sultana.