Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn wọ́gilé òfin tí Makinde fi de ẹgbẹ́ NURTW l’Oyo
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tó n jókòó nílùú Ìbàdàn ti wọ́gilé òfin tí Gómìnà Seyi Makinde fi de ẹgbẹ́ àwọn ọlọ́kọ̀ èrò níìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, NURTW.
Ile ẹjọ ni igbesẹ naa tabuku si ofin orilẹede Naijiria.
Gomina Makinde gbe igbesẹ yii lọjọ Kọkanlelọgbọn ọdun 2019, lẹyin to fẹsun kan NURTW pe wọn n da omi alaafia ru nilu,, ti ijọba si gba akoso gbogbo ibudokọ kaakiri ipinlẹ Oyo
Igbesẹ yii ni ko dun mọ ajọ naa ninu, ti wọn si morile ilẹ ẹjọ ni ọjọ kọkandinlogun oṣu keje, ti wọn si n pe fun pe ki ile ẹjọ wọgile igbesẹ ijọba ipinlẹ.
Ẹwẹ, ile ẹjo giga ti kọkọ yi ẹjọ naa danu lọjọ kẹtalelogun ọdun 2022, to si ni ko fẹsẹ mulẹ.
Ajọ NURTW pẹlu agbẹjọro rẹ, Femi Falana (SAN) kọri si ile ẹjọ kotẹmilọrun lọjọ kejilelogun oṣu kẹrin, ti wọn si jiyan pe ijọba ipinlẹ Oyo ko ni aṣẹ labẹ ofin lati fofin de ajọ labẹ iwe ofin Trade Union Act, CAP T14, ofin orilẹede Niajiria.
Ẹwẹ, agbẹjọro agba fun ipinlẹ Oyo, Abiodun Aikomo, jiyan pe ijọba ipinlẹ Oyo gbe igbesẹ yii nitori pe ajọ NURTW wa lara iṣoro alaafia nipinlẹ Oyo.
Ninu idajọ ẹlẹni mẹta ti adajọ Kenneth Amadi lewaju fun dajọ pe ijọba ipinlẹ Oyo kọ lati fi ẹri silẹ lati gbe lẹyin idi ti wọn fi fofin de ajọ NURTW.
“Mo wọgile fifi ofin de iṣẹ NURTW nipinlẹ Oyo. Bakan naa ni mo tun wọgile idajọ ile ẹjọ kekere ,” Adajọ Amadi ṣalaye.
Adajọ Biobele Georgewill, ti idajọ naa lẹyin, to si bu ẹnu atẹlu ọna ti ijọba ipinlẹ Oyo gba lori ọrọ naa.
O fikun pe bo ti lẹ jẹ pe ijọba ipinlẹ Oyo ni aṣẹ lati ri pe ofin fẹsẹ mulẹ, wọn gbọdọ ṣe ni ilana pẹlu ohun ti ofin gbe kalẹ.
Nigba ti a kan si ijọba ipinlẹ Oyo lori idajọ ile ẹjọ ati igbesẹ to kan lati ọdọ wọn, agbẹnusọ fun Gomina ipinlẹ Oyo, Sulaimon Olanrewaju ni ijọba ko ti ṣetan lati ṣo ohun kohun bayii lori idajọ ile ẹjọ.
Lọdun 2019 ni ijọba ipinlẹ Ọyọ kede pe oun ti fofin de ẹgbẹ awakọ ero nipinlẹ Ọyọ, NURTW, to si pasẹ pe eegun wọn ko tun gbọdọ sẹ mọ.
Lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ, olori osisẹ lọọfisi gomina lasiko naa, Oloye Bisi Ilaka salaye pe iwa idaluru ti awọn ẹgbẹ ọlọkọ ero yii n hu lawọn agbegbe kan nilu Ibadan lo fa sababi igbesẹ ijọba naa.
Ẹgbẹ awakọ ero NURTW nipinlẹ Ọyọ, ti figbe bọnu pe ki Gomina Seyi Makinde tu okun ofin to fi de awọn nitori aifararọ eto abo to n ba ipinlẹ Ọyọ finra losu karun ọdun 2019.
Alaga ẹgbẹ NURTW nipinlẹ Ọyọ lọdun 2019, Alhaji Abideen Olajide, ti gbogbo eeyan mọ si Ejiogbe lo parọwa bẹẹ ninu atẹjade kan to fisita, pẹlu afikun pe bi gomina Makinde se fofin de isọwọ sisẹ awọn asaaju ẹgbẹ ọlọkọ ero, ti di ọna ijẹ wọn lojumọ.
Nigba to n ba akọroyin sọrọ lọdun naa, alaga ẹgbẹ ọlọkọ ero nipinlẹ Ọyọ, Waheed Adeọyọ, ti gbogbo eeyan mọ si Ejiogbe, ẹni ti akọwe ẹgbẹ, Sunday Yeye gbẹnu rẹ sọrọ, salaye pe laipẹ ni awọn yoo pe ipade gbogbo ọmọ ẹgbẹ awakọ ero nipinlẹ Ọyọ, lati fi asẹ ijọba naa to wọn leti
Bakan naa ni Ejigbe tun nahun kesi Olubadan ilẹ Ibadan lasiko naa, Ọba Saliu Adetunji Aje Ogungunnisọ Kinni, lati bawọn rawọ ẹbẹ si Makinde pe ko tu okun ofin naa lọrun awọn nitori agba ti ko binu ni ọmọ rẹ n pọ.