Bí Goodluck Jonathan ó dupò ààrẹ ní 2027, òfin ni yóó sọ

Bí Goodluck Jonathan ó dupò ààrẹ ní 2027, òfin ni yóó sọ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà sọ pé ọ̀rọ̀ tí kò rújú, kìí kọṣẹ̀ létè ẹni.
Bí ètò ìdìbò gbogbogbo ọdún 2027 ṣe ń súnmọ́ etílé, onírúurú àwọn èèyàn ni wọ́n ti ń fi èrò wọn hàn lórí ètò ìdìbò náà.

Mínísítà tẹ́lẹ̀ rí fétò ìròyìn àti ìlanilọ́yẹ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Jerry Gana ti ní ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí ní Nàìjíríà, Goodluck Jonathan máa gbégbá ìbò láti dupò ààrẹ lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP lọ́dún 2027.

Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní ìlú Minna, ìpínlẹ̀ Niger níbi àpérò ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Gana sọ pé ààrẹ méjì ló ti ṣe ìjọba ní Nàìjíríà lẹ́yìn Jonathan tí àwọn èèyàn sì ti ń pòùngbẹ ìpadàbọ̀ Jonathan.

Ó ní Jonathan fi ipò ààrẹ Nàìjíríà sílẹ̀ lọ́dún 2015 nítorí ó ní ìgbàgbọ́ pé ẹ̀jẹ̀ ọmọ Nàìjíríà kankan kò tọ́ láti bá ètò ìdìbò lọ.
“Àwọn ọmọ Nàìjíríà ti rí ìyàtọ̀, ìyàtọ̀ tó fojú hàn láàárín ìṣèjọba Jonathan àti àwọn méjì tó ti ṣe ìjọba lẹ́yìn rẹ̀, tí wọ́n sì ń sọ pé kó padà sórí ipò
“Mo lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Goodluck Ebele Jonathan máa díje dupò ààrẹ lọ́dún 2027 lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, a sì ní láti gbáradì láti dìbò fún-un láti padà sípò ààrẹ.”

Nígbà tó ń júwe ẹgbẹ́ òṣèlú PDP bíi ẹgbẹ́ tó jẹ́ èyí tó gbájúmọ́ ọ̀rọ̀ àwọn aráàlú jùlọ, Gana sọ pé ó jẹ́ ẹgbẹ́ tó máa ń fún àwọn èèyàn láàyè láti yan olórí tó bá wù wọ́n.

Ó wòye pé èyí ló mú kí PDP ṣì jẹ́ ẹgbẹ́ tó gbajúmọ̀ jùlọ ní Nàìjíríà.

Lórí ọ̀rọ̀ pé ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ń ní àwọn ìdojúkọ kan lábẹ́nú, ó ní gbogbo ìfaǹfà tó ń wáyé nínú ẹgbẹ́ náà ni àwọn àgbààgbà ẹgbẹ́ ti yanjú, tó sì jẹ́ pé àwọn ti ń gbáradì fún iṣẹ́ tó wa níwájú wọn fún 2027.

Bákan náà ló rọ àwọn èèyàn láti wà ní ojú lalákàn fi ń ṣọ́rí, kí wọ́n fi ìbò lé ìjọba tó wà lóde kúrò lórí ipò, kí wọ́n sì fi ìbò dá Jonathan padà gẹ́gẹ́ bí ààrẹ.
Ẹ̀wẹ̀, iléeṣẹ́ ààrẹ ti wá fún Jerry Gana lésì lórí ọ̀rọ̀ bí wọ́n ṣe ní àwọn ọmọ Nàìjíríà kò ì tíì gbàgbé bí Jonathan ṣe ṣàjọba nígbà tó wà nípò ààrẹ.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ Tinubu, Bayo Onanuga fi síta lọ́jọ́ Ajé sọ pé àwọn ẹgbẹ́ alátakò ti ń kó ara wọn jọ láti tako Tinubu níbi ètò ìdìbò ọdún 2027 bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Tinubu ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti mú ètò ọrọ̀ ajé padà sípò.

Onanuga ní bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Jerry Gana ṣe sọ pé Goodluck Jonathan máa díje dupò lọ́dún 2027 lẹ́yìn ọdún méjìlá tó ti fipò náà sílẹ̀.

Ó ní ó pọn dandan kí wọ́n ṣèkìlọ̀ fún Jonathan láti yé jẹ́ kí àwọn èèyàn ti òun gbọ̀ngbọ̀n láti mú ìfẹ́ inú wọn wá sí ìmúṣẹ, tí wọ́n sì máa fi sílẹ̀ láàárín agbami gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣe lọ́dún 2015.

Ó wòye pé Jonathan le díje dupò ààrẹ tó bá wù ún nítorí ẹ̀tọ́ rẹ̀ ni àti pé ààrẹ Bola Tinubu ṣetán láti gbà á tọwọ́ tẹsẹ̀ sí ìdíje náà.

Ó fi kun pé Jonathan máa nílò láti gba ilé ẹjọ́ lọ nítorí àwọn adájọ́ ló máa sọ bóyá Jonathan, tí wọ́n ti búra wọlé fún ní ẹ̀ẹmèjì gẹ́gẹ́ bí ààrẹ ṣì ní ẹ̀tọ́ láti tún díje lábẹ́ òfin láti tún díje fún sáà kẹta.

Onanuga tún sọ pé Jonathan yóò tún nílò láti ṣàlàyé fáwọn èèyàn ohun tuntun tó ní láti ṣe lẹ́yìn ọdún mẹ́fà tó lò lórí ipò láì sí ohun kankan láti fi ṣàfihàn fún-un.

Ó ní lọ́dún 2010, owó tó lé ní $66bn ni Jonathan bá nínú àpò ìjọba tó jẹ́ ti owó ilẹ̀ òkèèrè àmọ́ kò ju $32bn tó kù nínú àpò náà nígbà tó máa fipò sílẹ̀ lọ́dún 2015.

Nígbà tí ètò ìdìbò bá ti ń bọ̀ ni onírúurú awuyewuye máa ń wáyé pàápàá lórí ẹni tó le gbégbá ìbò.

Lára awuyewuye tó máa ń wáyé ni bóyá ààrẹ àná ní Nàìjíríà, Goodluck Jonathan lẹ́tọ̀ọ́ láti díje dupò ààrẹ mọ́ lẹ́yìn òfin ètò ìdìbò ọdún 2022 tí ààrẹ Muhammadu Buhari gbé kalẹ̀.

Lára ohun tí òfin náà sọ ni pé ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá ti búra wọlé fún lẹ̀ẹmèjì fún ipò gómìnà tàbí ààrẹ yálà láti parí sáà ẹnìkan, kò lẹ́tọ̀ọ́ láti díje dupò náà mọ́.

Òfin yìí ló máa ń rú àwọn èèyàn lójú nípa bóyá Jonathan tún le díje fún ààrẹ Nàìjíríà nítorí wọ́n ti burá wọlé fún un ní ẹ̀ẹmèjì.

Àkọ́kọ́ ni láti parí sáà ààrẹ Umar Yar’adua tó jáde láyé lọ́dún 2009 àti lọ́dún 2011 nígbà tó wọlé ìbò ààrẹ.

Onímọ̀ nípa òfin, Ademola Owolabi sọ fún akọ̀ròyìn pé ìwé òfin Nàìjíríà máa ń ṣiṣẹ́ síwájú ni, kìí bojú wẹ̀yìn.

“Tí nǹkan bá ṣẹlẹ̀ ní àná, tí a ṣe òfin lónìí, òfin ta ṣe lónìí kò le mú nǹkan tó ṣẹlẹ̀ lánàá mọ́, tàná yẹn ti lọ nìyẹn.”

Owolabi sọ pé lásìkò tí Jonathan fi ṣe ààrẹ ní Nàìjíríà, kò ì tíì sí òfin pé ẹni tí wọ́n bá búra fún ní ẹ̀ẹmèjì kò ní le gbégbá ìbò mọ́.

O ní òfin tó wà nílẹ̀ nígbà náà ni pé èèyàn kò lè ṣe ààrẹ ju sáà méjì lọ.

Ó ní lẹ́yìn tí Jonathan kúrò lórí ipò ni wọ́n tó gbé òfin náà sílẹ̀, tí òfin náà kò sì lè mú Jonathan mọ́.

“Tí a bá fi ojú ìwé wò ó, ó máa jọ pé Jonathan kò ní lè díje dupò ààrẹ mọ́ nítorí òfin sọ pé ẹni tó bá tí wọ́n bá ti búra wọlé fún ní ẹ̀ẹmèjì kò ní lè dupò ààrẹ ṣùgbọ́n òfin yẹ wáyé nígbà tí Jonathan ti kúrò lórí oyè.

“Òfin wa kò le mú nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn mọ́, a kìí ṣe òfin fún àná tàbí ọ̀la. A ò le gbé òfin kalẹ̀ lọ́dún 2019 kí a ní kó mú nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ lọ́dún 2015.”