Gomina Fubara padà sípò lẹ́yìn oṣù mẹ́fà

Gomina Fubara padà sípò lẹ́yìn oṣù mẹ́fà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Òní ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù Kẹsàn-án ọdún 2025 ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers, Siminalayi Fubara, tó yẹ̀bá nípò lósù mẹ́fà sẹ́yìn yóò padà sípò náà, lẹ́yìn tí Ààrẹ Bola Tinubu fagilé ìkéde ìlú kò fararọ tó ṣe lórí Rivers lọ́jọ́ kejìdínlógún, oṣù Kẹta ọdún yìí.

Ẹ o ranti pe ikede ilu o fararọ to le Fubara kuro nipo, waye latari ija oṣelu to waye laaarin rẹ ati Nyesom Wike, Minisita olu ilu ilẹ wa, Abuja.

Nigba to si di ojumọ kan aroye kan ni Aarẹ paṣẹ pe ki Fubara fipo silẹ na, to si fi Ajagunfẹyinti Ibok-Ete Ekwe Ibas, ṣe Alabojuto ipinlẹ Rivers fun oṣu mẹfa.

Oriṣiiriṣii iṣẹlẹ lo waye laaarin oṣu mẹfa naa, ninu rẹ ni Ajagunfẹyinti Ibok-Ete Ekwe Ibas ti yan awọn eeyan ti yoo bojuto ijọba ibilẹ mẹtalelogun to wa ni Rivers lati ba a ṣiṣẹ.

Ninu rẹ ni Fubara ati Wike ti ni awon ti pari ija, iyẹn loṣu Kẹfa ọdun yii, ti wọn ṣepade pẹlu Aarẹ Tinubu l’Abuja.
Wọn yan alabojuto eto idibo ipinlẹ Rivers loṣu Kẹfa naa, o mu ariwo dani nitori wọn ni Ọmọwe Micheal Odey ti wọn yan sipo naa ki i ṣe ọmọ ipinlẹ Rivers, wọn ni Cross River lo ti wa.

Odey bẹrẹ iṣẹ rẹ loṣu Keje, o si kede pe ibo ijọba ibilẹ yoo waye yoo waye ni ọgbọnjo oṣu Kẹjọ.

Wọn dibo naa bo tilẹ jẹ pe awuyewuye pọ lori rẹ, ẹgbẹ APC lo si wọle ni ijọba ibilẹ ogun ninu mẹtalelogun.

Wọn bura fun awọn alaga ibilẹ wọle si ọfiisi, Ajagunfẹyinti Ibok-Ete Ekwe si bura fun awọn igbimọ ileeṣẹ ijọba kan.

Nigba to ku ọjọ diẹ ki iṣakoso Ibok-Ete Ekwe Ibas pari, o ṣeto kan to fi ka iye oṣiṣẹ ijọba ati awọn oṣiṣẹfẹyinti ni Rivers, titi kan awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ.

Ajagunfẹyinti Ibok-Ete Ekwe Ibas si kede pe oun ri i pe wọn fi kun owo oṣu awọn eeyan kan ju iye to yẹ kijọba maa san jade lọ.

O ni oun ṣe atunṣe si eyi, oun si ri owo to le ni biliọnu marun-un naira fi pamọ fun ipinlẹ naa.

Ṣugbọn ọpọ oṣiṣẹ ijọba lo tako eyi, wọn ni awọn ko ri owo oṣu Kẹjọ gba, titi kan owo ajẹmọnu awọn oṣiṣẹfẹyinti.

Adele olori oṣiṣẹ to ba wọn sọrọ, rọ wọn lati fi to ọga agba ileeṣẹ wọn leti fun atunṣe.

Ṣaa, Ajagunfẹyinti Ibok-Ete Ekwe Ibas, sọ pe oun yin ara oun fun iṣẹ toun ṣe ni Rivers lasiko idilemu naa.
Ireti ọtun pọ fun awọn eeyan ipinlẹ Rivers bi Fubara ṣe n gba ipo rẹ pada lẹyin oṣu mẹfa, ti awọn ile igbimọ aṣofin ibẹ naa yoo ṣe bẹrẹ iṣẹ pada.

Awọn ẹka kan bii Center for Human Rights and Accountability Network (CHRAN) ti ni ki Gomina Fubara gbe igbimọ kan kalẹ ti yoo tọpinpin bi wọn ṣe nawo ilu lasiko oṣu mẹfa ti Ajagunfẹyinti Ibok-Ete Ekwe Ibas fi di ile mu.

Adari CHRAN, Otuekong Franklyn Isong, sọ pe bi Aarẹ Tinubu ṣe da Fubara duro ko ba ofin mu.

O ni abala 305 ofin ilẹ Naijiria ti ọdun 1999 ko fun Aarẹ lagabra lati da gomina ti wọn dibo yan duro ati awọn igbimo ile aṣofin.

O fi kun un pe o yẹ ki Fubara fi idaduro oṣu mẹfa naa kun saa rẹ ni, o si yẹ ki ile ẹjọ to ga julọ da si I ki iru nnkan bẹẹ too tun waye.

Ṣugbọn awoye ati onimọ oṣelu, Olalekan Ige, sọ pe iyẹn kọ lo kan fun wọn ni Rivers bayii, o ni ohun to kan ni ki Fubara gbajumọ iṣẹ rẹ to ṣeṣẹ gba pada.

Ige ṣalaye pe iṣẹ pọ nilẹ fun gomina yii lati ṣe, awọn aṣepati iṣẹ to fi silẹ lasiko idaduro rẹ lo ni o yẹ ko lọọ bẹrẹ pada.

Ati bi idagbasoke yoo ṣe ba Rivers ju ti tẹlẹ lọ.

Awoye oṣelu naa ṣọ pe 2025 lo n tan lọ yii, 2026 ko si ni nnkan mi-in ti oloṣelu yoo fi ṣe ju imurasilẹ ibo 2027 lọ.

O ni yẹ ki gomina yii mọ pe oun ko ni asiko, ko si gbọdọ fi ti araalu naa ṣofo pẹlu.

Ṣugbọn ko tete bẹrẹ awọn eto ti yoo mu aye awọn eeyan ipinlẹ Rivers daa ju ti tẹlẹ lọ.