Ìpínlẹ̀ Niger ní àwọn oníwàásù gbọdọ̀ gbàṣẹ ìwáásù

Ìpínlẹ̀ Niger ní àwọn oníwàásù gbọdọ̀ gbàṣẹ ìwáásù

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣéwọ́n ní bí a ti í ṣe níbí, èèwọ̀ ni ní ibòmíràn èyí ló bí onírúurú awuyewuye tó ń wáyé lórí ìgbésẹ̀ tí ìjọba ìpínlẹ̀ Niger gbé pé gbogbo àwọn tí yóò máa ṣe ìwáásù ní ìpínlẹ̀ náà gbọdọ̀ kọ́kọ́ fi ìwáásù ránṣẹ́ sí ìjọba kí wọ́n tó ṣe é.

Níṣe ni ọ̀rọ̀ náà ti ń fa ìyapa ẹnu láàárín àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn àtàwọn aráàlú lórí pé ṣé ó lẹ́tọ̀ọ́ fún ìjọba láti ní ipa lórí ìwáásù táwọn onímọ̀ ẹ̀sìn yóò máa ṣe.

Ṣáájú ni gómìnà ìpínlẹ̀ Niger, Muhammed Umar Bago sọ nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pẹ̀lú iléeṣẹ́ TVC lọ́jọ́ Àìkú ti sọ pé àwọn gbé ìgbésẹ̀ náà láti ri pé àwọn mójútó báwọn èèyàn ṣe ń ṣe ìwáásù ní ìpínlẹ̀ náà.

Gómìnà Bago sọ pé kìí ṣe pé àwọn fi òfin de ṣíṣe ìwáásù bíkòṣe pé Àlùfáà tí yóò bá ṣe wáàsí lọ́jọ́ Ẹtì gbọdọ̀ kọ́kọ́ fi ohun tó fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí ránṣẹ́ sí ìjọba fún àyẹ̀wò àti ìbuwọ́lù.

Ó ní a ò lè sọ pé nítorí èèyàn jẹ́ àlùfáà, kí wọ́n máa lo àǹfàní náà láti máa ṣe àwọn ìwáásù èyí tó le máa ṣe àkóbá fáwọn èèyàn àti ìlú kí wọ́n rò pé nǹkan tó dára ni.
Ó fi kun pé ohun tí ìjọba ń ṣe ni láti kojú àwọn ìṣoro èyí tó ń fa àìsí ètò ààbò tó ń wáyé ní ìpínlẹ̀ náà.
Adarí àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ní ìpínlẹ̀ Niger, Umar Faruk Abdullahi sọ pé ìjọba gbé ìgbésẹ̀ láti ri pé ìjọba ṣe àfọ̀mọ́ báwọn èèyàn ṣe ń ṣe ìwáásù ní ìpínlẹ̀ náà.
Ó ní ìgbésẹ̀ náà kìí ṣe ohun tuntun bó ṣe jẹ́ pé ó ti wà lábẹ́ ètò “Preaching Act” ti ọdún 1983 tó sì jẹ́ pé wọ́n kàn ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣe àmúṣẹ rẹ̀ báyìí.

Ó ṣàlàyé pé gbogbo àwọn nǹkan tí ìpínlẹ̀ náà ń kojú ni wọ́n ṣe pinnu láti máa gba nǹkan táwọn àlùfáà bá fẹ́ ṣe ìwáásì lé lórí.

Ṣáájú nínú oṣù yìí, ó ní gbogbo àwọn àlùfáà ni wọ́n máa ní láti gba ìwé àṣẹ látọ̀dọ̀ ìjọba èyí tí wọ́n máa gbé síta láàárín oṣù méjì.

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, àwọn àlùfáà náà yóò gba fọ́ọ̀mù, kojú ìgbìmọ̀ tó ṣe ìwádìí, tí wọ́n sì ti máa buwọ́ lù wọ́n kí wọ́n tó lè ṣe wáàsí ní ìtagbangba.

“Tí a bá fi gbogbo rẹ̀ dá àwọn èèyàn, wàhálà yóò wà. Ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn jẹ́ ohun tí èèyàn gbọ́dọ̀ ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú rẹ̀. Ní Nàìjíríà, pàápàá ní ẹkùn àríwá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ tó ìṣòro tó ní í ẹ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ààbò ni wọ́n ń kojú. Bí àwọn àlùfáà kan ṣe máa ń ṣe ìwáásù wọn máa ń dá ìbẹ̀rù sílẹ̀.

“Boko Haram bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìwáásù, ISIS bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìwáásù. Boko Haram kò ì tíì wá sópin, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ló ti sọnù lórí rẹ̀. Nígbà tó yẹ kí ìjọba Borno ṣe àyẹ̀wò àwọn ìwáásù Muhammad Yusuf, wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀.”

Bákan náà ló tún ṣe àlàyé pé ní Mecca àti Medina àtàwọn orílẹ̀ èdè bíi Egypt àti Sudan, àwọn àlùfáà kìí dédé ṣe ìwáásù láì ṣe pé wọ́n gba àṣẹ lọ́wọ́ ìjọba àmọ́ tí ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ ní Nàìjíríà tó jẹ́ pé àwọn àlùfáà kàn máa ń ṣe ohun tó bá wù wọ́n.
Ahmed Ibrahim Khalil tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Malam Bala tó jẹ́ adarí àjọ “Center for the Study of Science and Technology in Religion” sọ pé ìgbésẹ̀ ìjóba náà kò tọ̀nà tó àti pé ó jẹ́ títẹ ètò ìjọba àwaarawa lójú mọ́lẹ̀.

Ó fi ìgbésẹ̀ ìjọba náà wé ọ̀rọ̀ òṣèlú, pé ọ̀pọ̀ wọn ló máa ń lo àwọn àlùfáà láti dé ipò òṣèlú àmọ́ tí wọn kìí fẹ́ kí ẹlòmíràn lò wọ́n àti pé ọ̀rọ̀ náà kìí ṣe ìpínlẹ̀ Niger nìkan bíkòṣe gbogbo Nàìjíríà.

Malam Bala gbàgbọ́ pé ìwáásù kìí ṣe ọ̀nà láti ṣi àwọn aráàlú lọ́nà tàbí jẹ́ kí wọ́n máa rí ìjọba ní ìlànà ọ̀tọ̀, tó sì ní ohun tí ìjọba nílò ni láti mójútó àwọn ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn tí wan bá fẹ́ mú àtúnṣe bá ọ̀rọ̀ ààbò nítorí ibẹ̀ ni wọ́n ti máa ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà jùlọ.

Ó fi kun pé lábẹ́ ètò ìṣèjọba àwaarawa, àwọn èèyàn ní àǹfàní láti sọ̀rọ̀ bó bá ṣe wù wọ́n, tí òfin Nàìjíríà fi ààyè gba ẹnikẹ́ni láti lọ sílé ẹjọ́ tó bá rip é èèyàn kan sọ̀rọ̀ òdì sí òun.

Ó wòye pé àwọn orílẹ̀ èdè bíi Saudi Arabia jẹ́ orílẹ̀ èdè ti ẹ̀sìn Islam ti gbilẹ̀, tí ọ̀pọ̀ wọn sì ń gba owó oṣù lábẹ́ ìjọba èyí tó le mú kí ìjọba máa rí ìwáásù tí wọ́n bá fẹ́ ṣe kí wọ́n tó ṣe é.

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, alága tẹ́lẹ̀ rí fún ẹgbẹ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi, Christian Association of Nigeria (CAN) ní ìpínlẹ̀ Niger, Ẹni ọ̀wọ̀, MS Dada sọ pé ọ̀rọ̀ náà kù sí ọwọ́ àwọn tó fẹ́ ṣe àmúṣẹ òfin náà lọ́wọ́.

Ó ní kò sí ohun tó burú níbẹ̀ tó bá jẹ́ ara ìta tí kìí ṣe ẹni tó ń gbé ìpínlẹ̀ Niger ni ìjọba ń sọ àmọ́ tó bá jẹ́ pé àwọn tó ń gbé ìpínlẹ̀ Niger ni, ìgbésẹ̀ náà kò dára rárá.

Ó fi kun pé ṣíṣe àmójútó ìwáásù kìí ṣe ohun tuntun ní ìpínlẹ̀ Niger tó sì jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ààbò ló tún jẹ́ kí ìjọba gbé e dìde. Ó ní òun kò rò pé gómínà náà jẹ́ ẹni tó máa gbájúmọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn.

Agbẹjọ́rò kan ní ìpínlẹ̀ Kano, Sulaiman Magashi sọ pé ó kù sọ́wọ́ àwọn ìpínlẹ̀ láti ṣe àmójútó ìwáásù àwọn àlùfáà láì fi nǹkan tí ìwé òfin Nàìjíríà.

Ó sọ fún akọ̀ròyìn pé ó sàn fún ìjọba láti ṣe àmójútó báwọn àlùfáà ṣe ń ṣe ìwáásù nítorí ìlànà kan nínú Islam èyí tí òfin Nàìjíríà náà fi ààyè gba àtúnṣe sí.

Abala kẹrin ìwé òfin Nàìjíríà fi ààyè gba èèyàn láti ṣe ẹ̀sìn tó bá wù ú tó fi mọ́ ẹ̀tọ́ pípolongo ẹ̀sìn.

“Èyí kò túmọ̀ sí láti máa ṣe ìwáásù tako ìwà ọmọlúàbí tàbí máa bú èèyàn èyí tó le bí ìwà jàgídíjàgan. Fún ìdí èyí, ó pọn dandan láti ṣe òfin lórí ṣíṣe ìwáásù tó dára, Sulaiman Magashi sọ.

Bákan náà ló ní ìjọba nílò láti pé àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn tí wọ́n bá fẹ́ gbé irú òfin bẹ́ẹ̀ kalẹ̀.

Ìpínlẹ̀ Niger kọ́ ni yóò kọ́kọ́ ṣe irú òfin yìí. Ṣáájú ni ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Kaduna ti buwọ́lu irú òfin báyìí àmọ́ ti wọn kò máa ṣe àmúlò rẹ̀.

Ní oṣù Kejì, ọdún 2025, Ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ Islam ní Nàìjíríà tí Sultan ìlú Sokoto, Muhammad Sa’ad Abubakar III pè fún ṣíṣe òfin láti máa ṣe àyẹ̀wò àwọn tó ń ṣe ìwáásù.