Ọ̀gbẹ́ni Olaoye déèdé pòórá nílé ìtura kan nílùú Akure
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ádùrá tí a máa ń ṣe ni pé kí á má rin àrin f’ẹsẹ̀sí.
Mọ̀lẹ́bí ọkùnrin kan, Ògbẹ́ni Olaoye Olatunde, tó jẹ́ igbákejì ọ̀gá àgbà ilé ẹ̀kọ́ girama kan nílùú Ọwọ ti ké gbàjarè pé ọkùnrin náà di àwárítì lẹ́yìn tó lọ fún idanilẹkọ ní ilé ìtura Sunview nílùú Akure.
Iyawo arakunrin naa salaye rẹ pe, ni ọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹjọ, ọdun 2025, ni ọkọ rẹ dagbere pe ohun n lọ fun idanilekọ kan n’iluu Akure, eyi ti wọn yoo ṣe ni ile itura Sunview.
Ajọ kan ti kii ṣe ti ijọba, Trace Project Akure pẹlu ajọsepọ Charakids Foundation lo ṣagbatẹru idanilekọ naa.
O sọ di mimọ pe, Ọgbẹni Olaoye pe ohun nigba to de Sunview fun Idanilekọ naa, ti wọn si jọ sọrọ lati ọjọ Aje ọsẹ naa titi ti di Ọjọru.
O ni ọkọ ohun ṣe ileri fun pe ohun yoo pade silẹ ni ọjọ Ẹti ọsẹ naa ni kete ti wọn ba pari idanilekọ
Ṣugbọn iyalẹnu nla lo jẹ fun gbogbo ẹbi naa pe wọn ko gbọ ohunkohun lati ọdọ Olaoye, titi di asiko yii, ti aago ipe rẹ lori foonu ko si lọ.
Igbese yi lo mu ki egbọn rẹ lọ si ile Itura Sunview lati mọ ohun ti o sẹlẹ, sugbọn iyalẹnu lo jẹ pe wọn ri aṣọ ati awọn ohun miiran to jẹ ti Olaoye ni ile itura naa, ti okunrin naa si di awati.
Awọn mọlẹbi naa, wa kesi ileeṣẹ Ọlọpaa lati se isẹ wọn bi isẹ ki wọn si ba wọn sawari ọgbẹni Olaoye Olatunde.
Lasiko ifọrọwerọ pẹlu ẹni to jẹ asoju ile itura naa, Arabinrin Oluwaseyi Adebayo, o fi idi rẹ mulẹ pe lootọ ni ajọ Trace Project Akure pẹlu ajọsepọ Charakids Foundation sagbatẹru idanilekọ naa ni ile itura naa.
Arabinrin Adebayo sọ di mimọ pe o to eniyan mẹrindinlọgọta to kopa nibi idanilẹkọ ọhun.
O wa salaye pe lasiko ti wọn fẹ ṣe ariya fun awọn to kopa nibi idanilẹkọ ni asalẹ ọjọ Ẹti ti wọn pari eto naa ni wọn ri wipe ẹni kan ko forukọ silẹ.
Arabinrin naa salaye pe awọn eniyan naa forukọ silẹ lati mọ ohun ti wọn jẹ tabi mu lasiko ariya naa.
Adebayo sọ pe nigba ti awọn fidirẹ mulẹ pe enikan ko forukọ silẹ, awọn fito awọn to sagbatẹru idanilekọ naa sọrọ.
“Wọn sọ fun wa pe ọkan lara awọn to kopa naa ti pada nitori o jẹ ọga ile ẹkọ to si nilo lati lọ ki ọwọ bọ iwe ki awọn olukọ le gba owo oṣu wọn.
O salaye pe lẹyin eyi ni awọn adari idanilekọ naa sọ fun wọn pe ki wọn lo kokoro to wa lọwọ wọn lati si ilẹkun ti okunrin naa sun si, ki wọn le ko awọn ẹru rẹ jade.
Adebayo sọ pe iyalẹnu nla lo jẹ nigba ti awọn mọlẹbi Ọgbẹni Olaoye kan si wọn pe arakunrin naa di awati.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Olushola Alayande sọ di mimọ pe wọn ti fi panpẹ ọba mu awọn mẹta lori iṣẹlẹ naa.
Alukoro naa to lọra lati salaye lẹkunrẹrẹ awọn ti wọn mu naa sọ pe, wọn ti kan si awọn alasẹ ile itura naa ti wọn si n samulo gbogbo ẹri to wa niwaju wọn lati sawari okunrin naa.
Alayande ni ileeṣẹ Ọlọpaa yoo ri daju pe wọn tu iṣu de isalẹ ikoko lori ọrọ naa.
O wa rọ enikeni to ba ni ẹri ti yoo ran ileeṣẹ Ọlọpaa lọwọ lori ọrọ naa lati fi sọwọ si wọn.