Adájọ́ kọ ẹ̀bẹ̀ Nnamdi Kanu
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ilé ẹjọ́ gíga ìlú Àbújá tó ń gbọ́ ẹjọ́ Nnamdi Kanu ti da ẹbẹ tí agbẹjọ́rò afurasí náà pé kí wọ́n gbé òun lọ sílé ìwòsàn ìjọba àpapọ̀ tó wà nílùú Àbújá fún ìtọ́jú.
Emmanuel Kanu, to jẹ aburo Nnamdi Kanu lo bura niwaju ile ẹjọ ọhun pe aarun ọkan to le gbẹmi ẹgbọn oun n da a laamu, o si nilo ko lọ sile iwosan ti wọn yo ti tọju rẹ lai fi akoko ṣofo.
Agbẹjọro Nnamdi Kanu, Uchenna Njoku sọ fun ile ẹjọ naa pe awọn agbẹjọro ijọba apapọ ti fun oun ni iwe ẹjọ tako ẹbẹ oun lati gbe Kanu lọ ile iwosan fun itọju amọ oun ko ti ri aaye lati wo iwe naa to ni oju ewe mẹtadinlogoji.
Njoku sọ pe oun nilo lati ka iwe ọhun daadaa ki igbẹjọ naa to le tẹsiwaju bo tilẹ jẹ pe isinmi lẹnu iṣẹ fun awọn adajọ yoo pari lonii, ti iṣẹ adajọ Adajọ Musa Liman yoo si pari iṣẹ rẹ lori ẹjọ naa fun igbẹjọ.
Ṣaaju ni adajọ Liman naa ti sọ pe oni ni oun yoo gbọ ẹjọ mọ nitori pe niṣe loun n duro fun adajọ to n gbọ ẹjọ naa tẹlẹ amọ to ti lọ fun isinmi lẹnu iṣẹ.
Adegboyega Awomolo to jẹ olori ikọ agbẹjọro ijọba apapọ sọ pe oun gba ohun ti Njoku sọ wọle nitori ko si akoko pupọ lati maa gba ọrọ naa bi ẹni gba igba ọti.
Nigba to n sọrọ, Adajọ Liman ni oun ti sọ ṣaaju pe o le ṣoro fun oun lati joko gbọ ẹjọ naa daadaa latari pe adele adajọ to lọ fun isinmi ni oun, ti asiko isinmi naa ko si ni pẹ pari.
O fi kun pe oun gba lati gbọ ẹjọ ọhun nitori ohun to yẹ ki wọn tete da si ni, ati pe o kan ọrọ eto ilera eeyan, eyii to le yọri si iku.
O ni oun yoo tari ẹjọ naa si akọwe ile ẹjọ, ti akọwe naa yoo si tare rẹ si adajọ James Omotosho, to n gbọ ọ ṣaaju oun.
Amọ o ni oun yoo kọ iwe pelebe kan sori iwe ẹjọ naa pe ki wọn tete yanju eyii to jọ mọ eto ilera Kanu nitori o ṣe koko, wọn si gbọdọ yanju rẹ ni kiakia.
Agbẹjọro kan ti ko fẹ ki a fi orukọ oun lede sọ fun wa pe ti adajọ Liman ba kọ iwe pelebe naa sori iwe ẹjọ ọhun, o ṣeeṣe ki adajọ James Omotosho joko lori ẹbẹ naa ṣaaju ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹwaa to n bọ yii to jẹ ọjọ ti wọn sun igbẹjọ ọhun si ṣaaju.
Ẹsun meje ọtọọtọ ni Kanu n kawọ pọnyin rojọ rẹ niwaju ile ẹjọ giga ilu Abuja bayii.
Awọn ẹsun naa da lori igbesunmọmi ati wiwa ninu ẹgbẹ agbesunmọmi.
Ọdun 2015 ni awọn agbofinro Naijiria kọkọ fi ṣikun ofin mu Kanu, ọdun naa si ni igbẹjọ rẹ bẹrẹ.
Nigba ti yoo di ọdun2017, ile ẹjọ fun ni beeli nitori ilera rẹ ṣugbọn o na papa bora lẹyin ti awọn ọmọ ogun ya bo ile rẹ niluu Umuahia, ipinlẹ Abia.
Lọdun 2021, wọn tun fi ṣikun ofin mu lorilẹede Kenya ti wọn si gbe wa si Naijiria pẹlu ṣẹkẹṣẹkẹ lati wa tẹsiwaju igbẹjọ rẹ.
Lati ọdun naa wa ni Kanu ti wa ni ahamọ DSS to si n lọ sile ẹjọ lati jẹjọ.
Amọ ṣa, afurasi naa ti sọ pe oun ko jẹbi gbogbo ẹsun ti ijọba Naijiria fi kan oun.