Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ló tú àṣírí agbára tí mo fi ológbò ṣe -Sunday Igboho

Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ló tú àṣírí agbára tí mo fi ológbò ṣe -Sunday Igboho

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní inú rẹ ni o mọ̀, ṣe gààyà fún inú ẹlòmíràn díá fún sóoróyè ọmọ aṣaworoko….
Bí ajìàágbara ọmọ Yorùbá nnì, Sunday Adeyemo (Igboho), ṣe ń tẹ̀síwájú nínú àbẹwò rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọba ilẹ̀ Yorùbá, ọkùnrin tó ń pè fún ìdásílẹ̀ orílẹ-èdè Yorùbá yíì ti tú àṣírí míràn.

Nigba to ṣabẹwo si Aafin Olowo ti ilu Owo, Oba Ajibade Gbadegesin (Ogunoye Kẹta), Igboho sọrọ nipa agbara rẹ tó fi ológbò ṣe, ti awọn ẹṣọ DSS pa loru ọjọ ti wọn ya bo ile rẹ niluu Ibadan loṣu Keje ọdun 2021.

Aafin Olowo ni Igboho ti sọ pe oun ni ologbo kan lootọ, eyi ti oun sọ aṣiri nipa rẹ fun ọrẹ oun kan to sunmọ oun pẹkipẹki.

Aṣiri naa lo ni ọrẹ òun náà tu fun awọn agbofinro DSS, ti wọn si ṣe bẹẹ pa ologbo naa nigba ti wọn fi ipa wọle, ti wọn wa we e laṣọ bi oku eeyan lẹyin ti wọn pa a tan.
“Nigba ti wọn fipa wọ ile mi, wọn fẹ pa mi ni, ṣugbọn wọn ko ri mi pa.

“Nigba ti mo ṣilẹkun yara mi fun wọn, wọn ri oloogbo mi lori ibusun.

“Ọkan lara awọn ọrẹ mi ti mo sọ aṣiri fun nipa ologbo náà, lo ti sọ fun wọn tẹlẹ pe wọn ko gbọdọ jẹ ki ologbo yẹn lọ.”

“Nitori ẹ, ni wọn ṣe pa ologbo naa ti wọn si we e laṣọ bi oku.

Wọn ba gbogbo ile jẹ, wọn pa ọkan lara awọn aburo mi ati ẹnikan, wọn si ba ti wọn lọ.”

“Awọn kan ti n gbe e kiri pe ifun mi ti jade sita, awọn kan ni ẹsẹ mi ni wọn kan, ṣugbọn ko sohun to jọ bẹẹ.

“Loootọ, wọn yinbọn si mi pupọ, ṣugbọn adua ẹyin baba mi gba lori mi.”

Bẹẹ ni Sunday Igboho ṣalaye nipa ikọlu ọdun kẹrin sẹyin naa.

O fi kun un pe atimọle loun wa lorilẹede Benin, ti mama oun fi ku nile.

Igboho sọ pe mama naa ro pe ijọba Tinubu yoo lo agbara lati tu oun silẹ kia ni, ṣugbọn nigba ti aarẹ gba jọba, toun ko si ri itusilẹ, mama oun dagbere faye.

Ọjọ keji lẹyin iku iya naa lo ni oun gba ominira.