Naira Marley ké sí ikò̩ o̩ló̩pàá
ìpínle̩ Eko láti se ìwádìí ikú Mohbad lé̩è̩kansíi
Mary Fágbohùn
Olorin Naijiria Azeez Fashola, ti a mo si Naira Marley, ti ro iko olopaa ipinle Eko lati teramo iwadii ohun to da iku olorin to wa labe re tele, Ileriuwa Oladimeji Aloba, ti a mo si Mohbad.
O se ikede yii lasiko to n ranti oro to so lori esun ti won fi kan an nipa lilowo ninu iku Mohbad ninu fidio kan lori ikanni YouTube re ni ojo Isegun.
Nigba to duro lori pe oun ko mo nnkankan nipa iku olorin naa, Naira Marley ni ki awon olopaa pada wa gbe oun ati ojugba re, Samsan Balogun, tawon eeyan mo si Samlarry, ati gbogbo awon miiran ti won fi esun kan pe won lowo ninu iku Mohbad.
O ni olopaa to ba se gbarale ni ki won fi sidi iwadii oro naa lasiko yii.
“Mo pada wa si Niajiria lati wa satileyin fun awon olopaa nitori mo ri pe won n nawo si wa. Nirori naa mo nilo lati pada wa ki won le mo pe mi o lowo ninu re, ki won si sofintoto eni ti won ba funra si ki idajo ododo le wa,”o so bee.
“Mo wa ni Panti fun osu meji. Leyin ti mo jade ni Panti, mo n ja fun iwe irinna mi, won mu lowo. Mo ni, o daa ti won ba beere oro lowo mi [lori iku Mohbad], sugbon ko si idi kan ti mo fi gbodo wa ni atimole. Mi o rii fun bii odun kan. Sugbon o daa. Awon kan dite, won fi mi sibe. Bi e se ri, won tile daruko olopaa to wa lori oro naa ni Panti. Won tun n soro nipa adajo.
“Ti e ba bi mi, maa so fun awon olopaa lati ko gbogbo wa. Ki won si fi olopaa to se gbarale sibe,” ni o so.
Naira Marley tun safihan pe oun ti yanju oro pelu agbejoro Mohbad lati fun ohunkohun to ba to sii fun eyikeyi ninu awon molebi re ti ile-ejo ba yan lati maa mojuto ile re.
E ranti pe Mohbad ku laisi eni to mo idi iku re ni ojo kejila osu kesan an 2023. Oga ile-ise orin re tele, Naira Marley, ati Samlarry ni won tokasi fun iku re.
Leyin esun yi, awon mejeeji ni eka iwa odaran ti ipinle to wa ni Panti, ti mole fun osu meji ni 2023 sugbon ti won fi won sile leyin ti won sanwo itanran.
Ore Mohbad lati kekere, Owodunni Ibrahim, ti a ni si Prime Boy, pelu ni won so mo oro nipa iku re sugbon ti won pada gba owo itanran lati fi sile.
Ninu iforo-wani-lenu-wo pelu eni to pe ara re ni ajafeto, VeryDarkMan ni Osu Keje 2025, Prime Boy se gbogbo esun ti won fi kan an, pe oun ba Mohbad ja laisi apa kankan lara re nigba ti won jo jade gbeyin (nibi ere D’General Bitters Ikorodu) ni ojo Kewaa Osu Kesan an 2023, saaju iku olorin naa.
Feyisayo Ogedengbe, noosi to gun labere eyi ti won ni o yori si iku Mohbad, peu si ero atimole.
Ninu oro awon Dokita meji ti won se ayewo okunfa iku ti won sise lotooto, ile-ejo ipinle Eko lori oro naa so pe iyoku ara Mohbad ti baje koja ki won le mo ohun pato to fa iku re.
Adajo, C.A. Shotobi, wi pe “iku re ko si asopo kankan pelu iwa ipa, sugbon aifiyesi ise ilera.”
Ile-ejo pase pe ki Director of Public Prosecutions, DPP, pe noosi, Feyisayo Ogedengbe lejo.