Do2dtun ké sí àwo̩n o̩mo̩ Naijiria tó lo̩ sí ilè̩-òkèèrè láti má se dé̩rùba àwo̩n tó wà nílé mo̩

Do2dtun ké sí àwo̩n o̩mo̩ Naijiria tó lo̩ sí ilè̩-òkèèrè láti má se dé̩rùba àwo̩n tó wà nílé mo̩

Mary Fágbohùn

Gbajumo kan lori ayelujara, Do2dtun ti koro oju si bi awon omo Naijiria ti won jo lo si ile-okeere se n gba awon to ku sile niyanju lati ma se daba pe awon naa fe wa si ile-okeere.

Ninu oro Do2dtun, o ni ayafi awon to ba ti pada wa si Naijiria ti won si n gbe be lowolowo, won ko gbodo mu ki irewesi ba awon ti won n lepa lati gbe igbese ti won gbe.

O jiyan pe awon ti won ti je anfaani latari kikuro ni Naijiria ko gbodo se idaleeko kankan lori bi ile-okeere se nira lati gbe nigba ti awon pelu ko ti pada wa lati dojuko nnkan tawon to wa nile n koju.

Do2dtun kowe pe, “Ti o ba ti japa, ma gba awon eniyan nimoran lori idi ti ko fi ye ki won wa mo. Ti o ko ba tii pada si Naijiria; o si n gbe ile-okeere, jowo gbenu dake. Ko to si o lati mu ki irewesi ba awon eniyan ti won n gbiyanju lati to ona naa. Fi imoran re si apo ara re. To ba le ju, pada wale. Je ki awon miran gbiyanju”.

Do2dtun tun tesiwaju ninu oro re ni bo se ni enu ate lu awon omo Naijiria ti won n lora dojuko awon olowo tabi awon gbajumo kan, koda nigba ti won ba se nnkan ti ko to.

O sapejuwe awon to n hu iru iwa bee bi pe “won n fi oro sabe ahon so” ati pe won ni “irori bi ti eru.”

Gege bi o se so, iwadii a maa fa owo aago eni seyin ati pe awon die ti won rowo mu naa ni yoo maa tesiwaju lati je anfaani nigba ti awon toku a maa to si lo.

O fikun un pe, “Ni Naijiria, ese ni lati dojuko olowo. E o ri bii eni to n foro sabe ahon so se n binu to, eni ti Olorun gbagbe, alaimokan; alatenuje; alailoye ati eni to ni irori bii ti eru ti won ri ara won bii awose yoo se gbeja ko o loju fun didojuko ko won nigba ti won se asise”.