Kò sí e̩se̩ inú Ìwé Mímó̩ tó tó̩kasí ìgbéyàwó só̩ò̩sì

Kò sí e̩se̩ inú Ìwé Mímó̩ tó tó̩kasí ìgbéyàwó só̩ò̩sì

Mary Fágbohùn

Amugbalegbe aare teleri, Reno Omokri, ti fesi si oro enikan to beere lowo re fun ilana Bibeli nipa ero lori igbeyawo ni soosi.

Reno fi atejade kan lori Instagram re, o salaye pe ko si ese Bibeli kan to tokasi igbeyawo soosi.

Esi re yi waye leyin ti Reno fi atejade kan lede lori Instagram nibi to ti soro lodi si bi okunrin kan se gbiyanju lati te ololufe re lorun nipa ‘kikunle’, sugbon ti won ko lati bu iru ola bee fun iya won.

Olumulo Instagram ti a mo si @jimmy_x_ so pe, “Fun idi eko nikan Baami Reno, se Bibeli satileyin eyi?”

Reno wi pe koda oro ti a mo si ‘soosi’ ko si ninu iwe mimo ti Giriki (Greek) sugbon ninu ogbufo re nikan lo wa.

“Jimmy owon, o se fun esi re. Se awon omo Afrika ni itokasi ninu Iwe Mimo saaju ki a to gba asa awon alawo funfun? Jimmy, se o bojumu fun mi lati fun o ni ese kan ninu Iwe Mimo lati mase nnkan ti ko si ninu Iwe Mimo fun o lati se”

“Se iwo ko mo pe ko si ese kan ninu Bibeli to tokasi igbeyawo soosi? Koda, oro naa ‘soosi’ ko si ninu Iwe Mimo. Inu ogbufo re nikan lo wa, sugbon ko si ninu ojulowo Koine Greek.” O dahun.
Gege bi o se so, igbeyawo to wa ninu Bibeli ni won se nile nitori oro molebi ni, kii se ti alufaa.

“Gbogbo igbeyawo ti won se ninu Iwe Mimo ni won se ni ile, nitori igbeyawo je oro molebi. Alufa ko nI ohunkohun se pelu igbeyawo. Nitori won n fe owo re, won da o riboribo nipa siso pe Yeshua (Jesu) lo sibi igbeyawo ni Kenaani. Bee ni, O lo. Sugbon bii Alejo, kii se ojise Olorun. Igbeyawo naa waye ni ile, kii se sinagogu.”

Reno kadi oro pe soosi bere bi ibi awon Keferi ti n josin ni Europe, kii se ibi ti won ti n se igbeyawo.