Àgbà ọba ni Aláàfin àti Ọọ̀ni, àwọn oníròyìn ló ń gba ọ̀rọ̀ yìí bíi ẹni gba igbá ọtí- Olúgbọ́n

Àgbà ọba ni Aláàfin àti Ọọ̀ni, àwọn oníròyìn ló ń gba ọ̀rọ̀ yìí bíi ẹni gba igbá ọtí- Olúgbọ́n

Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé wọ́n ní àìsìníbẹ̀ làì dá sí i,Olúgẹ̀bọ́n ti ilé Igbọ́n ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Ọba (Ọ̀mọ̀wé) Francis Olushola Àlàó ní púpọ̀ ohun tó fa rògbòdìyàn tó bẹ́ sílẹ̀ láàrin Aláàfin ti ìlú Oyo àti Ọọ̀ni ti ìlú ilé lfẹ̀ ló jẹ́ pé ó wá láti ọwọ́ àwọn oníròyìn.

Oba Olushola Alao lasiko to n ba akọroyin sọrọ jẹ ko di mimọ pe oun sunmọ awọn Ọba alade mejeeji yii, to si jẹ pe awọn mejeeji n da abo bo agbegbe ati itẹ wọn ni.

“Awọn oniroyin lo n gba a bi igba ọti. Onikaluku fẹ da abo bo itẹ wọn ni. Emi ju eyi lọ to n waye lo jẹ aifagbafagba ni ko jẹ ki aye gun.”

Olugbon ni nnkan pato ti oun fẹ ko di mimọ ni pe agba ni awọn ọba alade mejeeji, to si pe fun suuru lasiko yii.

“Ati Ooni, ati Alaafin, ki onikaluku ni suuru, nnkan ti mo le sọ niyen.”
Oba Olushola Alao ni suuru lo ṣe koko lasiko yii laarin awọn ọba mejeeji.

“To ba to akoko, awọn agbagba yoo da si ṣugbọn bayii, ẹ sinmi ariwo.”