Odù Ifá kìlọ̀ fún gómìnà Ademola Adeleke

“Odù Ifá kìlọ̀ fún gómìnà Ademola Adeleke kò fi ọgbọ́n yanjú wàhálà ìjọba ìbílẹ̀ l‘Osun, kò ṣọ́ra gidi kó má ba à sọ ipò gómìnà nù”

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn àgbà sọ pé ogun àwítẹ́lẹ̀ kò yẹ kí ó pa arọ tó bá gbọ́n.
Àkòrí fún ọdún ìsẹ̀ṣe ti ọdún 2025 ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ni ‘Bí Ọ̀ọ̀dẹ̀ ò dùn, bí ìgbẹ́ nìlú ú rí.’

Èyí ló ṣe àfihàn bí orílẹ̀èdè Nàìjíríà ṣe rí lásìkò yìí.

‎Eekan kan lara awọn oníṣẹ̀ṣe nipinlẹ Osun, Oloye Ifagbenusola Atanda, to jẹ Asiwaju Awo Agbaye, ti fidi akori naa mulẹ pé, bi ile ko ba dun ìlú ko le dùn, bi ìlú ko ba dun ipinlẹ ko le dun ati pe, bi ipinlẹ ko ba dun orile-ede ko le dun.

‎Oloye Atanda, tun tẹsiwaju pe, ọpọlọpọ ile lo ti di ahoro latari bi ipinlẹ ati orile-ede ṣe ri lasiko yii.

Bẹẹ si ni ọpọ awọn ọlọmọge lo tí di aṣẹwo latari bi orile-ede ko ṣe rọrùn.
‎Ninu ohun ti ifa sọ fun ọdun isẹse ọdun 2025 yii ni pe, ki a mọ fi ẹran ikún sọ ẹran Àgbọ̀nrín nù.

‎Gẹgẹ bii odu ifa ṣe sọ wi pe, ki Gomina Ademola Adeleke Ìpínlẹ̀ ọsun ko fi ọgbọ́n yanju wahala ọrọ ijọba ibilẹ ti o wa niwaju rẹ bayii.

‎Ifa tun tesiwaju pe, ki Gomina Ademola Adeleke ko sọra gidigidi ko mọ ba padanu ipo rẹ gẹgẹ bii gomina ipinlẹ ọsun.

Ko si mọ le ẹran ikun ko mọ ba sọ ẹran agbonrin nu.