Cubana ko̩jú Hellen pé kó gbé o̩mo̩ rè̩ wá sí Naijiria tó bá dáa lójú pé òun ni bàbá o̩mo̩
Mary Fágbohùn
Gbajumo onile ijo Naijiria, Pascal Okechukwu, ti a mo daadaa si Cubana Chief Priest, lekan sii tun ti so̩ pe oun ko lo ni omo to wa lowo omobinrin Kenya Hellen Ati.
Ninu ijiroro re pele Peller, ilumooka agboti naa ni to ba da Hellen loju pe oun ni baba omo naa ko gbe wa si orileede Naijiria, ju ki o maa fi esun kan kaakiri lori ayelujara.
Cubana Chief Priest ko oro Hellen danu, o ni ki enikan gbe omo re dani se iyebiye ju ki eniyan ni okuta iyebiye lo.
O pe Hellen gbe ko gbe omo ohun wa si Naijiria fun ayewo eje talo lomo (DNA), o ni jije baba se pataki, ati pe kii se ohun ti enikan le fi wa okiki lori ayelujara tabi gba esan.
Cubana Chief Priest sapejuwe awuyewuye naa bi oro ere lori ayelujara ati pe oun ko ka oro Hellen si.
“O so pe o bimo fun mi, o wa ro pe ona to dara ju lati pe akiyesi mi si eyi ni lati maa pariwo lori ayelujara. Ti o ba gbe omo mi dani, ohun ti o gbe dani ju okuta iyebiye lo. O wa n so pe owo eje lowo mi, pe mo n se 419, mo n gbe oogun oloro, sugbon o fe ki eni to n lo oogun fun o lowo lati toju omo,” o pegan eni to ni o bimo fun naa.