Ìgbésẹ̀ láti yan Awujale tuntun bẹ̀rẹ̀, ìdílé ọmọ oyè ń fápa jánú

Ìgbésẹ̀ láti yan Awujale tuntun bẹ̀rẹ̀, ìdílé ọmọ oyè ń fápa jánú

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà sọ pé má tọjú mi yànmí mọ́ ẹbọ, kò ṣe wí sínú, àti pé èèyàn tó bá dákẹ́ wọ́n ní tara rẹ̀ yóó bá dákẹ́ ni tí yóó sì jẹ rà mọ́ onítòún nínú., bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ rí pẹ̀lú ìgbésẹ̀ yíyan ọmọ oyè tuntun sí ipò Awùjalẹ̀ tilẹ̀ Ìjẹ̀bú.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ọjọ Kẹtala osu Keje ọdun 2025 ni Awujalẹ ti Ijebu Ode, Ọba Sikiru Kayode Adetona waja, ti wọn si sin-in ni ọjọ naa ni ilana ẹsin Islam.

Ni bayii, ijagudu ti bẹrẹ lati yan ọmọ oye tuntun sipo rẹ laarin idile oye to n jọba ni Ijebu Ode.

Amọ idile kan laarin awọn idile to n joye ọba ilu Ijebu naa, ti n fapa janu lori iyansipo ọba to bẹrẹ naa.
Mọlẹbi Adeyemi niluu Ijebu-Ode, eyi to jẹ ẹka idile Anikilaya, lo ti n fi aidunnu wọn han si bi wọn ṣe ni wọn yọ orukọ awọn kuro ninu ọmọ oye to le du ipo Awujalẹ ilẹ Ijebu.
Gẹgẹ bi molẹbi Adeyemi ṣe ṣalaye, wọn ni ọmọ oye ni awọn, agba si lawọn pẹlu.

Ati pe idile naa ni Ọba Sikiru Adetona, Awujalẹ to waja laipẹ ti wa.

Atẹjade kan ti Adedeji Ademola Adeyemi lati idile naa fi sita, sọ pe awọn eeyan kan ti yi itan pada bayii lati abala idile oye Anikilaya.

Wọn ni wọn ti yọ orukọ Adeyemi kuro ninu ẹka ọmọ oye n’Ijebu-Ode, eyi ti ko yẹ ko ri bẹẹ.
Ninu alaye Adedeji Ademola Adeyemi nipa idile to ni wọn yọ orukọ wọn kuro yii, o ni Adeyemi Anikilaya ni Arẹmọ ọba to dagba ju ninu awọn ọmọ ọba Anikilaya Saagun, to si kọkọ jẹ ọba.

Ogbagba ati Ademolu ni wọn jẹ aburo ọkunrin lẹyin rẹ bo ṣe sọ.

O fi kun un pe, “Ọmọọba Ademola Aiyegbajeje Adeyemi ni wọn yan sipo Awujalẹ lẹyin ti Ọba Daniel Adesanya (Gbelegbuwa II) waja ni 1959, ṣugbọn o ni oun ko fẹ.

“Aburo rẹ, Ọmọọba Mubashiru Adedipupo Adeyemi, to jẹ Baba fun Oloogbe Ọba Sikiru Adetona, si fa ọmọ rẹ ti i ṣe Sikiru kalẹ fun ipo ọba naa, lati idile Adeyemi Anikilaya kan naa. Awọn afọbajẹ tẹwọ gba a, o si di Awujalẹ ni ọdun 1960.”

Bẹẹ ni apa kan atẹjade ẹbi Adeyemi wi.

Ẹbi naa ni awọn ko gba bi awọn eeyan kan ko ṣe fẹẹ fi agba fun idile Adeyemi gẹgẹ bii igun to dagba ju lọ.

Wọn ni kaka ki awọn to wa nidii ọrọ naa ṣe ẹtọ, niṣe ni wọn gbe ipo olori fun ọmọkunrin keji.

Ati pe wọn tun fi awọn meji mi-in ti wọn ki i ṣe ọmọ oye kun un.
Gẹgẹ bi Adeyemi ṣe wi, “Ko yẹ ki idile ọmọ ọba Mabadeje, Adekoya Ofirigidi ati Adeire Adeewu wa lara awọn ti wọn yoo fi kun un idije sipo Awujale.

Awọn wọnyi ni wọn ni ọmọ Ọba Anikilaya Saagun Figbajoye ni wọn, ti baba wọn jọba ni 1821, ṣugbọn awọn ko mọ wọn.

“Awa idile ọmọ oye Adeyemi, fidi ẹ mulẹ, pe arọmọdọmọ Adeyemi Anikilaya, ni wa. Oun si ni Arẹmọ to dagba ju ninu awọn ọmọ Ọba Anikilaya Saagun Figbajoye, to jẹ Awujale Ijebu Ode titi di 1821.”

Ṣaa, awọn ẹbi Adeyemi ni awọn rọ awọn eeyan lati ma ṣe gba ohun ti awọn eeyan kan n gbe kiri ninu ẹbi gbọ.