Makinde ṣàbẹ̀wò sí Fresh FM iléeṣẹ́ rédíò Ayefele tó jóná

Makinde ṣàbẹ̀wò sí Fresh FM iléeṣẹ́ rédíò Ayefele tó jóná

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àdúrà tí ẹ̀dá máa ń gbà náà ni pé kí n tí a kò rò kó má ba ohun tí à ń rò ní dáa dáa jẹ́.Èyí ló mú kí Gómìnà Seyi Mákindé ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ó ṣàbẹ̀wò sí Fresh FM Ìbàdàn, ilé iṣẹ́ rédíò gbajúgbajà akọrin ẹ̀mí, Yinka Ayefele, tó jóná lálẹ́ ọjọ́ Ẹtì tó kọjá.

Lasiko abẹwo rẹ ni Makinde ti ṣeleri lati ṣe iranwọ fun ileeṣẹ redio naa ki wọn le maa tẹsiwaju igbohunsafẹfẹ wọn.

Gomina ipinlẹ Oyo ni ileeṣẹ redio Fresh FM n ko ipa pataki nipa gbigbe iroyin gidi jade fun araalu
‘Emi funra mi ati ijọba ipinlẹ Oyo yoo ṣe iranwọ fun ileeṣẹ redio Fresh FM.

Mo fi dá wọn loju pe, a ko ni jẹ ki wọn kuro lori afẹfẹ fun igba pipẹ rara,” Makinde lo sọ bẹẹ.
Makinde kẹdun pẹlu Ayefele lori dukia ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu to ṣofo nibi ijamba ọhun.
Gomina ipinlẹ Oyo sọ pe itaniji ni iṣẹlẹ ijamba ina naa jẹ fun ipinlẹ Oyo lori ọna ati wa ojutuu si iṣẹlẹ pajawiri papaa julọ ijamba ina.
Makinde ni oun yoo sọ asọyepọ pẹlu awọn adari ileeṣẹ panapana ipinlẹ Oyo lori ati ro wọn lagbara lati le maa pa iru ina to jo ileeṣẹ redio Fresh FM lọjọ iwaju.

Gomina ipinlẹ Oyo ko ṣai fi idunnu rẹ han pe ẹni kankan ko ba iṣẹlẹ naa lọ.

Gomin ani ”ka ni pe awọn panapana ni irinṣẹ to to ni, wọn o ba lagbara lati pa ina yii.

Ara awọn nnkan ti mo ti ri pe a ni lati ṣiṣẹ lori rẹ niyẹn.

Si awọn alaṣẹ ati atawọn oṣiṣẹ Fresh FM, mo fẹ ki ẹ dupẹ lọwọ Eledua wi pe ko si ẹni to ba iṣẹlẹ naa lọ.”

Ninu ọrọ rẹ, Ayefele dupẹ lọwọ gomina fun abẹwo to ṣe si ileeṣẹ redio rẹ to jona ati ileri iranwọ to ṣe pẹlu.

Bakan naa tun ni gbajugbaja akọrin ẹmi ati pedepede naa tun dupẹ lọwọ gbogbo awọn ololufẹ Fresh FM fun atilẹyin wọn.

Ṣaaju ni agbẹnusọ ileeṣẹ redio Fesh FM, Samson Akindele, fidi rẹ mulẹ pe yara igbohunsafẹfẹ Fresh FM ati ti Blast FM 98.3 jona gan an.

O fikun ọrọ rẹ pe irinṣẹ igbohunsafẹfẹ, yara t’awọn akọroyin ti maa n ṣiṣẹ at’awọn irinṣẹ mere-mere mii naa jona rau rau.