Tiwa Savage setán láti se ìgbéyàwó

Tiwa Savage setán láti se ìgbéyàwó

Mary Fágbohùn

Gbajumo olorin, Tiwa Savage ti safihan pe o ni lokan lati tun igbeyawo se.

Lasiko to n soro ninu iforo-wani-lenu-wo kan to n lo kiri ayelujara, Savage kerora pe oun ko ni ololufe mii eni odun marundinlaadota.

Iya omo kan naa gba pe bi o se soro fun oun lati ri oko naa le je nitori erongba to ga to ni nipa eni ti yoo fe.

O pinnu pe iru oko ti o n fe gbodo je omode ki o si lowo ti ko si ni isoro pelu bibi omo kan saaju.
“Mo si n wa omo eni kan. Mi o ni eyikeyi [ololufe]. Mo ro pe nitori awon nnkan ti mo ni lokan lo fa idaduro yii. Boya ki n gbe wa sile die.

“Mo n wa enikan to ni oko ofurufu aladaani, to je omode; eni ti obinrin kan ko yo lenu fun omo nitori ara mi ko le gba eyi,” o so bee.

E o ranti pe Tiwa Savage se igbeyawo pelu alakoso re tele, Tunji Balogun, ti a mo si Teebillz, ni 2013, sugbon won pinya ni 2018 leyin ti won kuna lati di alafo iyato ara eni laarin won. Won bi omokunrin kan ti won pe oruko re ni Jamil.