Odunlade, Mr Latin, Kunle Afod àtàwọn òṣèré mii ń ṣèdárò Sunday Akinremi Chief Kanran tó jáde láyé

Odunlade, Mr Latin, Kunle Afod àtàwọn òṣèré mii ń ṣèdárò Sunday Akinremi Chief Kanran tó jáde láyé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọjọ́ tí a bá kú là á dère, èèyàn ò ṣunwọ̀n láàyè. Àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ lágbo òṣèré tíátà Yorùbá n ṣèdárò akẹgbẹ́ wọn, àgbàọ̀jẹ̀ òṣèré tó lapọ́njá, Alàgbà Sunday Akinremi tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Chief Kánran ẹni tó papòdà kúrò láyé lánàá ọjọ́ Ẹtì ọjọ́ kẹẹ̀dóógún oṣù Kẹjọ ọdún yìí.

Ọgbẹni Bolaji Amusan, to jẹ aarẹ ẹgbẹ awọn oṣere TAMPAN, Odunlade Adekola, Kunle Afod atawọn oṣere mii ti n fi ọrọ ibanikẹdun ransẹ si ẹbi oloogbe.

Adura ni Ọgbẹni Amusan tawọn eeyan mọ si Mr Latin gba fun gbajugbaja oṣere to doloogbe naa loju opo Instagram rẹ.

Ninu ọrọ tiẹ, Kunle Afod sọ loju opo Instagram rẹ pe ”o si nira fun mi lati gbagbọ pe Chief Kanran ti di oloogbe titi di aarọ oni.
A si jọ sọrọ ni bii ọjọ mẹrin sẹyin lori iṣẹ ti a fẹ jọ ṣe papọ lọsẹ to n bọ.

Mo ṣakiyesi pe inu Chief Kanran dun lọjọ ti a jọ sọrọ yii.

A fi bi mo ṣe gbọ pe Chief Kanran ti dagbere faye!

Agbaọjẹ oṣere ni Chief Kanran i ṣe, ki Eleduwa tẹ wọn si afẹfẹ rere.”
Adura naa ni Odunlade Adekola ba fun agbaọjẹ oṣere to doloogbe loju opo Instagram rẹ.

Adekola gbadura wi pe ki Ọlọrun tẹ Chief Kanran si afẹfẹ rere.