Àwo̩n òsèré sèdárò Chief Kanran
Mary Fágbohùn
Gbajumo osere Naijiria, Olusegun Akinremi, ti a mo ninu ere si Chief Kanran, ti je Olorun nipe.
Osere naa ni iroyin jade pe o mi eemi ikeyin ni eni odun mejilelaadorin ni aaro ojo Eti.
Seun Oloketuyi, gbajumo agberejade, lo kede iku osere naa ninu atejade kan lori Instagram.
“Gbajumo osere, Segun Remi ku ni aaro ojo Eti,” o kowe.
Ekunrere iroyin nipa iku re ni ko ti si letigbo oniroyin titi di akoko iroyin yi.
Chief Kanran, eni to je oruko agboole ni ile ise fiimu Yoruba, ni a mo fun ipa to ko bii General Philips ni abala ketala ninu eto mohunmaworan TV Megafortune.