2026 Hajj: N8.5m ni owó àkọ́kọ́ san ní ìpínlẹ̀ Eko

2026 Hajj: N8.5m ni owó àkọ́kọ́ san ní ìpínlẹ̀ Eko

Yínká Àlàbí

Ajọ to n seto irin ajo lọ si ilẹ mimọ Meka ni ipinlẹ Eko (Lagos State Muslim Pilgrims Welfare Board) ti kede pe fọọmu ilẹ mimọ naa ti wa ni tita. Wọn si ti seto bi awọn to ba lero lati lọ se maa san owo naa ni ẹẹmẹta ko le ba rọ wọn lọrun.
Wọn kede pe ẹnikẹni ko gbọdọ san owo kankan fun aladaani bi ko se apo ikowosi ti Lagos State Muslim Welfare Board, ki wọn si mu iwe ti wọn fi san owo naa lọ ẹka igbowo wọle ati jade ni ọfiisi ajọ naa.
Atẹjade yii waye lẹyin ipade gbogbo awọn to n sakoso eto Hajj ni ipinlẹ kọọkan waye ni ilu Abuja gẹgẹ bi ọga alukoro eto naa, Ogbeni Taofeek Lawal ati akọwe agba, AbdulHakeem Ajomagberin se gbe e jade ni ọjọ isẹgun yii.
Ajọ eto Hajj yii rọ awọn eniyan to ba fẹran lati tẹle awọn lọ ki wọn san owo ki awọn le seto ibi ti wọn maa de si, ounjẹ wọn ati awọn eto alaye ilẹ mimọ naa. Ajọ yii ni awọn si maa n fẹ tete seto ki ibi ti awọn eniyan ti awọn ba ko lọ ma baa jinna si Haram ni Meka ati Medina.