Àgbàrá òjò Ikorodu: Gbadebo Rhodes – Vivour gbàjo̩ba Eko nímò̩ràn
Nigba ti Iṣejọba ba kuna: Idaamu Ọgbara Ikorodu ati aikakun Ijọba ipinlẹ Eko: Asiwaju kii sa. Wiwa ojutu si wahala niṣẹ aṣiwaju rere – GRV
Nipa ajalu burúkú kan waye nilu Ikorodu latari omi ọ̀gbàrá nla to ya kaakiri ile, to si ba dukia jẹ, o tun fi ọpọlọpọ silẹ laini ibi aabo tabi ibùsùn.
Ajalu naa to yẹ ko gba idahun pajawiri lẹsẹkẹsẹ lọwọ Ijọba Ipinle Eko, o ṣe ni laaanu, o si tun jẹ ohun iyalẹnu nigba ti kọmisọna ipinlẹ Eko fun eto ayika ati awọn orisun omi gba awọn olugbe agbegbe tọrọ naa kan lamọran pe ki wọn kuro ni agbegbe naa.
Idahun ti kọmisọna fii yii kii ṣe ti ibanilọkan jẹ nikan, o tun ṣe afihan iru iṣakoso ìjọba ipinlẹ Eko, iṣakoso to ni aibikita si iya ti awọn eniyan doju kọ.
Eyi kii ṣe ajalu adayeba, o jẹ afihan kudiẹkudiẹ iṣejọba labẹ ẹgbẹ oṣelu APC ti n dari ipinle Eko.
Ibeere to wa nilẹ bayii ni pe, nígba ti kọmisọna ni ki awọn eeyan fi ile wọn silẹ, ibo ni ki wọn lọ? Ṣé wọn pese aafin ọba fun wọn ni, abi agbala awọn oloye abi ọgbà awọn ọlọpaa ni wọn ni ki wọn maa lọ.
Ko sibi meji ti wọn yoo lọ ju oju popona lọ, wọn yoo wa maa wọ sun kiri, abi nibo ni ki ẹni ti ko nile lori maa lọ?
Iṣoro agbara ojo nilu Ikorodu kii ṣe ohun tuntun, igba gbogbo ni awọn olugbe ibẹ maa n ṣe aroye ti awọn onimọ nípa ayika naa si n ṣe ikilọ.
Ọpọlọpọ atunṣe to jẹ ọna abayọ ni awọn amoye ti la kalẹ fun ìjọba sugbọn ko si eyi ti wọn mulo ninu rẹ.
Gbogbo koto ida omi nu lo ti di pa ti rogbodiyan omi yale agbára ya sọọbu ko si ni ojutu lọdọọdun.
Awọn ohun to yẹ kí ijọba ṣe
Asiko ti to fun ijọba ipinlẹ Eko ati ẹgbẹ oṣelu APC lati ji si ojuse wọn,idagbasoke kii ṣe nipa awọn afara ati awọn ọkọ ofurufu nikan; bi kii ṣe nipa awọn eniyan, obinrin ti o padanu ile itaja rẹ sinu agbàrá ojo, ki ni ko ṣe, awọn ọmọde ti o sun lori ilẹ tutu n kọ, awọn idile ti ko si ibi ti wọn yoo sun n kọ?
Ti ijọba ko ba le ri ojutuu si rogbodiyan naa, awọn ọmọ ipinlẹ Eko lero pe o yẹ ki wọn laaanu àwọn eeyan loju kii se ki kọmisọna wa ni ki awọn eeyan fi ile wọn silẹ lai pese ibi ti wọn yoo maa gbe.
Awọn ohun ti o yẹ ki ìjọba ṣe
* Ojutu ni kiakia ati awọn ibugbe ti aralu le gbe fungba diẹ
Ijọba ipinlẹ Eko le fi awọn ileewe ijọba ṣe eto ile ni kíákíá fún àwon eeyan ki wọn gbe fun igba diẹ naa, wọn tun le lo awọn gbọgan nla fun wọn.
Ijọba ni lati pese ounje, omi mimọ, itọju ilera, ati ibusun fun awọn eniyan tọrọ kan.
* Ijọba ni lati ṣe agbeyẹwo gbogbo agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹ:
Wọn ni lati ran awọn ajọ eleto pajawiri si awọn agbegbe ti ìṣẹ̀lẹ̀ naa ti ṣẹ, ki wọn si ṣe koto idaminu si awọn ibi to nilo rẹ bakan naa ni ki wọn ko gbogbo koto idaminu to ba ti di pa.
* Atilẹyin Pẹlu Owo
Ijọba nilo ati pese owo tabi owo san diẹdiẹ ti ko ni ele lori fun gbogbo awọn ti ọrọ naa kan.
Ijọba ipinlẹ Eko ko gbọdọ da awọn eeyan naa da bukata wọn, olori gbọdọ ran araalu lọwọ ni, wọn ko tun gbọdọ maa ṣe ikede ti yoo bawọn lọkan jẹ ju bo ti wa lọ.
Thomas Hobbes ṣe ikilo nipa awujọ ti ko ni adehun awujọ, nibi ti ijọba ti kuna lati daabo bo awọn eniyan rẹ.
Ikilọ yẹn kii ṣe amọran mọ, o ti n ṣẹlẹ ni awọn agbegbe wa.
Ẹ jẹ ko di mimọ fun iṣakoso ìjọba ipinlẹ Eko labẹ asia ẹgbẹ oselu APC pe :
Asaaju ki sa, ojutu si rogbodiyan ni asaju rere ma n wa nigba gbogbo.
Ẹ jẹ ki atẹgun alafia fẹ si awọn mẹkunnu
Ipinlẹ Eko nilo ohun to dara
Ikorodu nilo amojuto to ye koro
Awọn eniyan ibẹ nilo olori to n ṣíṣẹ fun wọn ki ṣe eyi to n ṣíṣẹ tako wọn