Ìjọba àpapọ̀ ṣakiyesi ayédèrú oṣiṣẹ 3,598 pàṣẹ ayẹwo tuntun.
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé wọ́n ní ogun àwítẹ́lẹ̀ kìí pa arọ tó bá gbọ́n.
Àjọ ìjọba àpapọ̀ tó wà fún ètò ìgbanisíṣẹ́ tí jáwé akìwọwọ fún àwọn òṣìṣẹ́ bíí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ ó lé pẹ́sẹ́pẹ́sẹ́ tíkò báwọn kópa níbi àyẹ̀wò ọdún 2021 láti tètè kó
gbogbo ìwé ẹ̀rí ìdánimọ̀ tó ṣàfihàn wọn bí ojúlówó òṣìṣẹ́ lábẹ́ ìjọba àpapọ̀ èyí tí yóó bẹ̀rẹ̀ ,parí láàrin 18-25 Oṣù kẹjọ ọdún 2025.
Àǹfààní àtúnyẹ̀wò yìí ni yóó wáyé káàkiri àwọn
ẹ̀ka ilé-iṣẹ́ àti lájọlájọ bíí ilé-iṣẹ́ ètò ọ̀gbìn,ètò ààbò,ètò ìdájọ́, ètò ẹ̀kọ́ àti àwọn mìíràn.
Ìwé kan tí wọ́n fi síta ní ọjọ́ kẹrin oṣù kẹjọ tó tẹ àkọròyìn lọ́wọ́ sọ pé kí
àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn ó ṣàyẹ̀wò orúkọ wọn lójú òpò àjọ ọ̀hún àti pé wọ́n tún lè rí àyẹ̀wò orúkọ wọn ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ wọn.
Ìròyìn ọ̀hùn ṣàfikún rẹ̀ pé
àwọn òṣìṣẹ́ náà gbọ́dọ̀ wá pẹ̀lú ojúlówó àti ẹ̀dà gbogbo ìwé ẹ̀rí wọn tó fi dórí àwọn ojúlówó àti ẹ̀dà ìwé àgbéga tí wọ́n fi
wà nípò.
Àjọ nàá tẹnumọ́ ọ pé, ẹni tí ò bá yọjú ,kò yàtọ̀ sí ẹni tó fi ìlànà èrú gba iṣẹ́ .Wọ́n ní àwọn tó kàn
jùlọ ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ ìròyìn
(592,ètò ẹ̀kọ́ (506), nígbà tí ẹ̀ka òṣìṣẹ́(440).
Àjọ náà kádìí rẹ̀ pé, àìyọjú òṣìṣẹ́ yòówú lè mú kí onítọ̀ún pàdánù iṣẹ́ rẹ̀.