
Àsírí tú! Àṣé àwọn ọmọ Igbo ló run ilẹ̀ Igbo kìí se Fulani – Soludo
Yínká Àlàbí
Gomina ipinlẹ Anambra, alagba Charse Soludo to tun je gomina ile Banki gbogbogbo (CBN) tẹlẹ ni orileede yi ti sọrọ soke. O ni, o to gẹẹ, awọn ni lati pariwo ara awọn sita. O ni pẹlu iwadii ati awọn ti ọwọ awọn agbofinro ti tẹ.
“Ida ọgọrun un din boya ẹyọkan (99.9%) ọmọ Igbo lo n ji ọmọ Igbo ẹgbẹ rẹ gbe. Aṣe awọn lo wa ninu igo to n je jin-in. Afi ki Ọlọrun dari ji wa pẹlu ariwo Fulani darandaran ti awọn n pa lojoojumọ”.
“O ma se o! awọn ọmọ iya mi ni wọn ri jiji eniyan gbe bii isẹ sise to lo lowo lori ju, eyi buru jọjọ lati maa wa owo ni ọna epe. Loootọ lo dara ki gbogbo aye mọ ọmọ Igbo bii akinkanju sugbọn kii se bii ti ole, ajinigbe ati ipaniyan to gbode kan”.
Soludo ni bi wọn n sọrọ nipa awọn to n gbe egbo igi oloro tabi Yahoo Yahoo, awọn ọmọ Igbo naa ni awọn n ba nibẹ, o ni eyi doju tini lọpọ. Ipade Anambra town hall ni Amerika ni gomina ipinlẹ naa ti ba awọn ọmọ Igbo to wa nibẹ sọ ootọ ọrọ. O ni gbogbo agbara ti awọn naa ba ni ni ki wọn sa lati ba awọn ọmọ iya awọn sọ ootọ ọrọ.
“Awon kan naa lo n lọ gbe ounjẹ fun awọn onisẹ ibi yii ninu igbo, awọn kan lo n fun wọn lomi mu , bẹẹ si ni awọn kan n ta wọn lolobo iye ti awọn olowo aarin awọn ni ati ibi ti wọn n rin si lati le ri wọn ji gbe”.
Ariwo yii gan an ti de ori ẹrọ ayelujara pe ki gbogbo awọn oniroyin ati ijọba apapọ ba awọn ipinlẹ Anambra ati Imo pẹlu awọn ipinlẹ to ku kede fun gbogbo aye pe, awọn ilu nla kọọkan ti dahoro nipasẹ awọn ọmọ Igbo to n ji ni gbe. Wọn ni awọn ilu nla bii Orlu, Ihiala, Isseke pẹlu gbajugbaja ọja ibẹ lo ti dahoro, ko si ẹyẹ ni awọn ilu naa mọ.
Gbogbo nnkan ni awọn to se fidio naa fi bura ti o ba jẹ irọ ni awọn n pa. Wọn nilo iranlọwọ ijọba apapọ lati ran awọn lọwọ pẹlu awọn agbofinro to gbona janjan.