Ìlànà ofin ni a fi mú Sowore, a kò sì fìyà jẹ ẹ́ – DCP Olumiyiwa Adejo̩bi

Ìlànà ofin ni a fi mú Sowore, a kò sì fìyà jẹ ẹ́ – DCP Olumiyiwa Adejo̩bi

Yínká Àlàbí

Ileesẹ ọlọpaa ti da gbaju-gbaja aja-fẹtọ-ọmọniyan lohun pe awọn ko mu u lai tẹle ofin. Wọn ni ọwọ ofin ni awọn fi mu u, awọn si fi ẹsun naa kan an pe o yi iwe bẹẹ lo si lọwọ si ayederu ayelujara pẹlu awọn ẹsun miiran. Ko si ọwọ lile ninu ohun ti a fi mu u, a ko si fi iya kankan jẹ ẹ.
Omoyele Sowore ni awọn olutẹle rẹ se iwọde fun ni ọjọ Ẹti, ọjọ kẹjọ, osu kẹjọ ọdun yii. Wọn ni ki ileesẹ ọlọpaa fi silẹ kiakia nitori pe mimu rẹ ko tẹle ofin. Wọn se iwọde yii ni Abuja, Eko, Osogbo ati awọn ilu kọọkan.
Igbakeji kọmisọna ọlọpaa DCP Olumuyiwa Adejobi salaye pe ko si ohun ti o tilẹ jọ ọwọ lile rara nitori pe awọn mọ ofin, bẹẹ ni awọn ko si gbọdọ lu ofin naa ni abala (Anti torture Act, 2017) ti ilẹ yii.
Kayode Egbetokun to jẹ ọga patapata awọn ọlọpaa ni ki iwadii to nipọn maa lọ labẹnu idi ti Sowore fi we apa kan bi ẹni ti iya ti jẹ ki wọn si fun oun ni iwadii kiakia.
Ileesẹ ọlọpaa fi Sowore silẹ ki ọjọ mejidinlaadọta to pe. Awọn si fi silẹ pẹlu beeli to ni awọn ẹlẹri ninu lati le tun pe e nigba ti awọn ba tun nilo rẹ gẹgẹ bi o se wa ninu iwe ofin ilẹ wa ni abala (section 35 (4) 1999) karundinlogoji.