Wọ́n ti fòfin de Wasiu Ayinde láti má wọ bààlúù fún oṣù mẹ̀fa
Fẹ́mi Akínṣọlá
Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ tó mú gbajúmọ̀ onífùjì, Wasiu Ayinde di ẹni tó ń dínà mọ́ bàálù pé kò ní ín fò , iléeṣẹ́ tó n rí sí ìrìnàjò afẹ́fẹ́ lórílẹ̀ èdè yìí ti fòfin de Máyégún ilẹ̀ Yorùbá húnọ̀ pé kò lè wọ ọkọ̀ òfurufú fún oṣù mẹ́fà ní Nàìjíríà.
Nigerian Civil Aviation Authority (NCAA), gbe igbesẹ yii lẹyin ti ọga olorin Fuji naa duro niwaju baaluu to n bọ l’Ekoo lati Abuja lọjọ Iṣẹgun.
Ni ibamu pẹlu aṣẹ Minisita to n ri si irinajo ofurufu lorilẹede yii, Agbẹjọro agba; Festus Keyamo, ni NCAA fi fofin de K1.
Ninu atẹjade ti Keyamo fi soju opo X rẹ l’Ọjọbọ lori iṣẹlẹ naa lo ti ni igun mejeeji ti ọrọ naa kan lo jẹbi.
Minisita naa sọ pe Wasiu to lọ dena de baaluu huwa to tako alaafia.
O ni bẹẹ si ni awọn awakọ baaluu naa to gbera lai tẹle ofin irinna niwaju ẹni to dena de wọn jẹbi pẹlu.
Minisita sọ pe oun ki awọn alaṣẹ ileeṣẹ naa ti wọn tete fun awọn awakọ meji naa ni idaduro titi ti wọn yoo fi pari iwadii lori iwa ti wọn hu.
Keyamo ni ṣugbọn Wasiu paapaa ko gbọdọ lọ lai jiya itapasofin to hu ọhun.
Bayii ni Minisita naa paṣẹ pe ki wọn fi orukọ Wasiu Ayinde si abala awọn ti ko ni i le wọ ọkọ ofurufu eyikeyi lasiko yii fun oṣu mẹfa.
Bi ileeṣẹ ọlọkọ ofurufu kan nilẹ yii tabi nibikibi ba tapa si ofin yii, ti wọn gbe Wasiu rin irinajo, kele ofin yoo gbe wọn ni Festus Keyamo sọ.
O ni ijọba yoo gbẹsẹ le iwe aṣẹ ti ileeṣẹ bẹẹ fi n ṣiṣẹ ni.
Bakan naa ni Oludari agba to n ri si alaafia awọn onibaara nileeṣẹ NCAA, Michael Achimugu, sọ l’Ọjọbọ pe gbogbo awọn to jẹbi ọrọ yii ni yoo foju wina ofin.
”Bi a ṣe n wi yii, oṣu mẹfa gbako ni arinrinajo yii ko fi ni I le fo loke ni Naijiria.”
Achimugu lo sọ bẹẹ.
Bi awọn kan ṣe n sọ pe Wasiu lẹnu, o si mọ Aarẹ Tinubu bi ẹni mowo, ko le gba a silẹ ninu eyi gẹgẹ bi Achimugu ṣe wi.
O ni Aarẹ Tinubu paapaa fẹran idajọ ododo ati iwa ẹtọ
Ìlúmọ̀ọ́ká akọrin Fuji, Wasiu Ayinde Kwam 1, ti fesi si iroyin to n lọ pe, o hu iwa ibajẹ ni papapọ ọkọ ofurufu ilu Abuja, lọjọ karun un, oṣu Kẹjọ.
Ṣaaju ni iroyin sọ pe Kwam 1 gbiyanju lati gbe ọti lile wọ inu baalu ValueJet kan to n rinrinajo lati Abuja lọ si Eko, to si kuna lati gbọ gbogbo alaye awọn oṣiṣẹ baalu.
Iroyin ọhun ninu atẹjade ti ajọ to n mojuto irinajo baalu, FAAN fi sita ṣalaye pe Wasiu Ayinde da ọti le awọn oṣiṣẹ baalu lori, eyi to mu ki wọn o le e jade pe ko ni wọ baalu.
Lẹyin eyi ni akọrin naa duro niwaju baalu pe ko ni i gbera, to si jẹ pe diẹ lo ku ki baalu naa kọlu u nigba to n gbiyanju lati fo.
Amọ ninu atẹjade ti agbẹnusọ Wasiu Ayinde fi sita, o ni iroyin to le ṣi ni lọna ni pe oun da omi alaafia ru ni papakọ ọkọ ofurufu.
Agbẹnusọ fun K1, Kunle Rasheed, sọ pe K1 ko fi asiko kankan hu iwa to le fi ẹmi ẹnikẹni sinu ewu, tabi tapa si ofin irinajo ofurufu.
O ni omi mimu lasan lo wa ninu nnkan ti Wasiu gbe da ni, tako iroyin to ni ọti lile lo wa ninu rẹ.
“Omi ti wọn fun un ni ibudo isinmi ni papakọ lasiko to n duro de asiko ti baalu rẹ yoo gbera lo mu da ni.
“Gbogbo igbiyanju rẹ lati ṣalaye eyi si lo ja si ofo.”
Bakan naa ni agbẹnusọ K1 ṣalaye pe irọ patapata ni iroyin to sọ pe olorin Fuji duro niwaju baalu tabi da irinna duro.
“Ẹni to n rinrinajo ofurufu nile ati nilẹ okeere ni agba olorin naa, to si ni oye nipa ilana to de iru irinajo bẹẹ.”
O ni ka ni lootọ ni Kwam 1 ṣẹ, awọn alaṣẹ papakọ ati oludari ileeṣẹ baalu ValueJet, ko ni i ma bẹ olorin naa tabi yọnda baalu aladani lati gbe e pada si Eko.
Kunle Rasheed sọ pe awakọ baalu naa lo n gbe iroyin ofege kiri nitori pe wọn ti gbẹsẹ le iwe aṣẹ iṣẹ rẹ.
Ajọ to n ṣe amojuto awọn papakọ ọkọ ofurufu ni Naijiria, Federal Airports Authority of Nigeria (FAAN), ti fi ẹsun kan gbajugbaja akọrin Fuji, Wasiu Ayinde, ti ọpọ eeyan tun mọ si KWAM 1, pe o da ọti si awọn oṣiṣẹ ọkọ baalu lara ni papakọ Nnamdi Azikiwe Airport niluu Abuja, lọjọ Iṣẹgun.
Ajọ FAAN sọ ninu atẹjade kan ti oludari ẹka ibaraalu sọrọ ati ẹtọ araalu, Arabinrin Obiageli Orah, fi sita pe ihuwasi Ayinde tako ilana irinajo ofurufu.
Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, wọn ni iwadii ti awọn kọkọ ṣe, ṣafihan rẹ pe Wasiu Ayinde n rinrinajo lati ilu Abuja l si Eko, pẹlu baalu ileeṣẹ ValueJet, nibi to ti gbiyanju lati gbe nnkan olomi ti ko lo ‘lorukọ’ wọ inu baalu, tako gbogbo ikilọ ti awọn oṣiṣẹ eleto aabo fun un, to fi mọ ti ọga awakọ baalu.
“Gẹgẹ bi ofin irinna, nnkan olomi to ba ti pọ ju 100ml lọ, ko le wọ inu baalu, ayaafi to ba jẹ pe iru nnkan bẹ wa fun ilera, ti ẹni to ni i si ṣafihan rẹ bo ṣe yẹ.”
Gbogbo alaye yii ni FAAN sọ pe wọn ṣe fun KWAM 1, ṣugbọn to kọ lati tẹle e.
Iṣẹlẹ naa ko tan sibẹ rara. Iroyin sọ pe nigba ti awọn oṣiṣẹ alaabo sọ fun un pe ko duro si ẹgbẹ kan naa fun iwadii, “eero baalu naa kọ̀, to si da nnkan olomi to gbe dani le oṣiṣẹ naa lori.
Ẹyinọrẹyin ni iwadii fihan pe, ọti lile ni, amọ to fi ọgbọn rọ sinu nnkan amomitutu.
Kia ni ọrọ naa ti di ariwo, eyi to mu ki olori awọn awakọ baalu fun irinajo naa da di, ṣugbọn bakan naa ni ọrọ ri, akọrin naa kọ̀ lati gbọ nnkan to n sọ.
“Lẹyin ti Balogun awọn awakọ ti fidirẹ mulẹ pe, gbogbo eto ti to fun irinajo naa lati bẹrẹ, o paṣẹ pe ki wọn o ti ilẹkun baalu naa.
Ṣugbọn iroyin sọ pe niṣe ni Wasiu Ayinde bọ si iwaju baalu naa, to si kọ lati kuro.
Fọnran fidio kan to n lọ kaakiri ori ayelujara ṣafihan bi baalu naa ṣe fẹ gbera eyi to mu ki gbogbo eero to fi mọ awọn oṣiṣẹ adari irinajo sa asala fun ẹmi wọn.
Diẹ lo ku ki baalu mu ori Wasiu Ayinde gun, nitori pe bo ṣe ri pe baalu n gbera lo sare sa si ẹgbẹ.
Iṣẹlẹ yii mu ki irinajo naa kọkọ duro naa, nitori pe awọn alaṣẹ papakọ ọkọ ofurufu ko gba awọn awakọ baalu naa laaye lati wakọ, ti FAAN si da awakọ mejeeji duro loju ẹsẹ.
Bakan naa ni awọn oṣiṣẹ alaabo mu KWAM 1 lọ fun iwadii, ki wọn o to yọnda rẹ lẹyin asiko diẹ́.
Ajọ FAAN sọ pe iwadii ṣi n lọ lori iṣẹlẹ naa, to si ṣe atẹnumọ rẹ pe, oun ko ni I faramọ iṣẹlẹ to le dunkooko mọ aabo tabi ta epo si aṣọ aala irinajo baalu ni Naijiria.
Ki ni ileeṣẹ ValueJet sọ lori iṣẹlẹ naa?
Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ baalu ValueJet fi sita lori ayelujara ni irọlẹ Ọjọru, wọn ni lọgan ni iṣẹlẹ naa waye ni awọn ti da gbogbo oṣiṣẹ baalu ti ọrọ kan duro fun igba diẹ, titi iwadii abẹnu lati mọ koko ohun to fa iṣẹlẹ naa, ati lati dena iru rẹ lọjọ iwaju, yoo fi pari.
Ọpọlọpọ eeyan lo ti n sọrọ lori iṣẹlẹ naa lori ayelujara. Bi awọn kan ṣe n bu ẹnu atẹ lu gbajugbaja olorin naa pe o hu iwa itiju, ni awọn kan n sọ pe ko yẹ ki awakọ baalu naa gbera nitori pe o le ṣe ijamba fun awọn to wa lori ilẹ.