Erin ya bo oko l’Ógùn
Yínká Àlàbí
Awọn agbebọnrin lo gba’jọba oko ni ilẹ Hausa nigba ti Erin o jẹ koloko o l’oko bẹẹ ni ko jẹ ki olodo o lo s’odo ni agbegbe Itasin-Imobi ni ijọba ibilẹ Ijẹbu-East ni ipinlẹ Ogun.
Awọn ara agbegbe naa ni isoro Erin yii ti to bii ọdun mẹrin bayii ti wọn ti n yọ wa si oko ti wọn si maa n le awọn kuro l’oko. Wọn ni eyi to mu ẹmi Musa Kalamu lọ lo jẹ kayeefi fun gbogbo awọn ara agbegbe naa.
Alukoro ọlọpaa ipinle Ogun, ọgbẹni Lanre Ogunlowo ni agọ ọlọpaa ipinlẹ naa mọ sii. Awọn si ti kan si ajọ ijọba ipinlẹ Ogun to ni igbo naa. Ajọ naa salaye pe ọgba ẹranko naa lo ni gbogbo igbo naa sugbọn bi idagbasoke se n de ni awọn agbẹ n sun mọ igbo naa.
Ọgba ẹranko naa ni wọn n pe ni “Queen Elizabeth Elephant Section”. Awọn alabojuto ọgba naa ni gbogbo ohun to ba gba lawọn maa n fun un lati ma se jẹ ki iru rẹ sẹlẹ mọ. Korede Musa to jẹ ọmọ oloogbe naa lo n salaye ohun toju awọn ri loko nigba ti awọn Erin mẹfa ya bo oko ti wọn si gbẹmi baba oun.
Eni ori yọ o dile ni awọn agbẹ agbegbe naa se, wọn ti fi oko naa silẹ patapata bayii.