Ó di 2031 kí ipò Ààrẹ tó kan apá Àríwá.

Ó di 2031 kí ipò Ààrẹ tó kan apá Àríwá.

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìpàdé alágbára ọlọ́jọ́ méjì gbáko èyí tó kó àwọn ojúùmi tó ọ̀rọ̀ ìlú nínú òṣèlú Naijiria sínú ti wáyé niluu Kaduna, níbi ti wọ́n ti ìgbéwọ̀n iṣẹ́ Ààrẹ Bola Tinubu fún ọdún méjì sí orí ìwọ̀n.

Ninu ipade naa ni Sẹnetọ George Akume; Akọwe ijọba apapọ ti ṣalaye pe o di 2031 ki ipo aarẹ to kan apa Ariwa.

Ọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii ni ipade ti ẹgbẹ Sir Ahmadu Bello Memorial Foundation gbe kalẹ naa waye, pẹlu aṣoju lati awọn ipinlẹ mọkandinlogun lati Ariwa ati Abuja.

Nigba to n jiṣẹ Aarẹ Bola Tinubu,George Akume ṣalaye pe ileri Aarẹ Tinubu to ṣe pẹlu eto Renewed Hope ti n wa si imuṣẹ.

O fi kun un pe awọn eto naa gbọdọ maa tẹsiwaju lai si idaduro kankan titi di 2031.
Ninu ọrọ rẹ, Akume ran awọn oloṣelu ilẹ Hausa to n mura silẹ fun ipo aarẹ ni 2027 leti pe ko ti i kan wọn.

Aṣoju aarẹ naa sọ pe bi a ba tẹle ilana pinpin ipo aarẹ, ko ni i kan apa Ariwa titi di 2031.

“Ni 1999, awọn oloṣelu apa Ariwa bii Solomon Lar, Adamu Ciroma, Abubakar Rimi ati Jerry Gana, fẹnu ko pe pinpin ipo agbara laaarin ara wa lo le mu alaafia wa.

“Bo si tilẹ jẹ pe wọn ko kọ ọ silẹ, ẹnu ko le e lori sibẹ naa. Fun idi eyi, o di 2031 ko too kan Ariwa.”

Akume lo sọ bẹẹ.

O rọ awọn eeyan Oke Ọya lati ṣe suuru titi ti yoo fi kan wọn.

“Ẹ jẹ ka ni suuru, Naijiria ko ni i parẹ ko too di 2031.

Nigba to ba kan wa, orilẹede yoo mọ.’
Malam Nuhu Ribadu,Oludamọran lori ọrọ aabo ni Naijiria toun naa wa nibi ipade yii, kin Geoge Akume lẹyin.

Nigba to n gboriyin fun Aarẹ Tinubu, Ribadu sọ pe ikọlu awọn ikọ apaayan;Boko Haram ati ija ẹlẹyamẹya ti dinku ninu iṣakoso Tinubu ti ko ti i ju ọdun meji lọ.

Ribadu sọ pe iyatọ to gbooro lo wa ninu eto aabo bayii, ti a ba fi we ti ijọba to kuro nipo naa.

Fun apẹẹrẹ, o ni eeyan 1,192 ni wọn pa ni Kaduna labẹ ijọba ana, awọn to le lẹgbẹrun mẹta 3,348 ni wọn si ji gbe bi Ribadu ṣe sọ.

O le ni ẹgbẹrun marun-un eeyan to padanu ẹmi nipinlẹ Benue bi Ribadu ṣe wi, ni deede asiko yii ninu ijọba to gbesẹ.

O ni ṣugbọn adinku to foju han gidi lo ti ba ikọlu ati ijinigbe bayii labẹ ijọba Tinubu.

Oludamọran lori eto aabo naa tẹsiwaju, pe eyi ṣee ṣe pẹlu aṣẹ ti Tinubu pa fun awọn ẹṣọ alaabo lati ri i pe wọn ṣẹgun igbesunmọmi.

O ni eeyan 11,259 ti wọn ji gbe loṣu Karun-un ti gba itusilẹ latari iṣẹ awọn ṣọja ni Ariwa-Iwọ-Oorun.

Ribadu sọ pe ọpọ awọn olori agbesunmọmi ati awọn ọmọ ẹgbẹ wọn ni awọn ẹṣọ alaabo Naijiria ti pa ni Zamfara, Kaduna ati ipinlẹ Katsina.

Gbogbo awọn eto idagbasoke mi-in ti Aarẹ Tinubu tun n ṣe, wa lara idi ti iṣakoso naa fi gbọdọ maa tẹsiwaju, ti agbara yoo si wa ni Guusu ilẹ yii di 2013, bi Malam Ribadu ṣe sọ.

Ninu awọn eeyan to kin itẹsiwaju ipo aarẹ Naijiria lẹyin lati wa nilẹ Yoruba ni ẹgbẹ Afẹnifẹre ati eyi ti a mọ si The Middle Belt Forum.

Akọwe eto ninu ẹgbẹ Afẹnifẹre, Kole Omololu, ṣalaye pe o daa ki ipo aarẹ ṣi wa ni apa Guusu ilẹ yii di 2031.

O ni fun dọgban-dọgba ati alaafia ni eto pinpin igbo agbara wa fun.

Omololu sọ pe bi wọn ṣe n sọ fun wọn l’Oke Ọya lati ṣe suuru di 2031 yoo mu irẹpọ wa lẹyin ohun gbogbo.

Bakan naa ni Bitrus Pogu, Aarẹ ẹgbẹ Middle Belt Forum, kin ijọba apapọ lẹyin lori aba pe ki awọn Ariwa ṣe suuru di 2031.

Bakan naa ni ẹgbẹ oṣelu APGA, sọ pe eto rere ni bi ipo aarẹ ba tẹsiwaju ni Guusu Naijiria.
Akọwe ijọba tẹlẹ, Babachir Lawal, ninu ọrọ tirẹ, sọ pe bii igba ti eeyan n fi ẹnikeji ṣe yẹyẹ ni ọrọ ti Akume ati Aarẹ Tinubu n sọ.

Babachir sọ pe Aarẹ Tinubu funra rẹ lo ru ofin pinpin ipo agbara, bẹẹ lo yi ilana ki aarẹ jẹ Musulumi, ki Igbakeji rẹ si jẹ Kristẹni pada.

Akọwe ijọba tẹlẹ naa sọ pe ko tọ si APC to ti da nnkan ru fun araalu lati maa paṣẹ apa ibi ti agbara yoo lọ.

Ọ fi kun un pe ko si akọsilẹ kankan to ni dandan ni ki aarẹ tun ti Guusu wa ni 2027.

Ni ti ẹgbẹ oṣelu APGA, awọn faramọ ipe naa to ni ki aarẹ wa lati apa Guusu ni 2027.

PDP ni tiẹ sọ pe aala ni yoo fi oko ọlẹ han ni 2027.

Wọn ni ọmọ Naijiria ni yoo fi ibo sọ ẹni ti wọn ba fẹ ko di aarẹ wọn.