Ìgbìmọ̀ Afọbajẹ n’Íbàdàn kéde Rashidi Ládọjà bíi Olúbàdàn Kẹrìnlélógójì
Fẹ́mi Akínṣọlá
Orí tí yóó dé adé,ọrùn tí yóó lèjìgbà ìlẹ̀kẹ̀, ìbàdí tí yóó lo mọ́sàa àṣọ ọba tí
i taná yanranyanran, inú agogo ní tií wá.
Àwọn Àgbà Oyè ilẹ̀ Ìbàdàn, tí wọ́n tún jẹ́ Ìgbìmọ̀ Olúbàdàn, ṣe àkànṣe ìpàdé l’áàfin Olúbàdàn tó ń bẹ ní Òkè-Àrẹ̀mọ l’ówùúrọ̀ ọjọ́ kẹrin (ajé), oṣù Kẹjọ ọdún 2025
Níbi ìpàdé náà ni ìgbìmọ̀ Olúbàdàn ti kéde Gómìnà tẹ́lẹ̀rí n’ípìnlẹ̀ Ọyọ , Ọba Sẹ́nétọ̀ Raṣidi Adéwọ̀lú Ládọjà gẹ́gẹ́ bíi Olúbàdàn ìkẹrìndínlógójì.
Balogun Olubadan, Ọba Tajudeen Ajibola, lo kọkọ darukọ Ọba Ladọja gẹgẹ bii ẹni ti oye Olubadan kan, ko to di pe Ọba Eddy Oyewole kin ọrọ Balogun lẹyin.
Igbesẹ ti o kan bayii naa ni ki igbimọ Olubadan fi orukọ Ọba tuntun ṣọwọ si Gomina Ṣeyi Makinde ki akanṣe eto ifinijoye ati gbigba ọpa aṣẹ to bẹrẹ ni pẹrẹu.
Igbesẹ yii waye lẹyin ọjọ kọkanlelogun ti gbogbo ilẹ Ibadan ti n kẹdun ipapoda Olubadan ana, Oba Owolabi Olakulehin to re iwalẹ aṣa lọjọ keje oṣu keje ọdun yii.
Ipade naa ni yoo waye ni Aafin Olubadan, to wa ni agbegbe Oke Aremo niluu Ibadan.
Ọsẹ to kọja ni igbimọ ọhun ti fi iwe ransẹ si awọn ọmọ igbimọ naa, lati kede fun araalu pe ipo Olubadan ti sofo, ti wọn yoo si kede ẹni ti yoo gba ipo naa gẹgẹ bii aṣa ilẹ Ibadan.
Atẹjade ti Balogun ilẹ Ibadan, Ọba Tajudeen Ajibola fi ranṣẹ si awọn akọroyin tọka rẹ wi pe, aago mọkanla owurọ ni ipade naa yoo waye.
Ipade yii n waye lẹyin ti wọn ti fi ọjọ mọkanlelogun daro ipapoda Olubadan to waja, Ọba Owolabi Olakulehin.
Gbogbo awọn Oloye Agba nilẹ Ibadan ni ireti wa wi pe yoo o kopa nibi ipade naa.
Lati igba ti Olubadan ana ti waja ni ẹni ti oye naa kan, Ọba Ladọja ti n gba oriṣiriṣi alejo ni ile rẹ to n bẹ niluu Eko, gẹgẹ bi awọn eeyan ṣe n fi tilu-t’orin ṣe abẹwo si ile rẹ to n bẹ niluu Ibadan naa.
Ọjọ keje oṣu Keje ọdun 2025 ni wọn kede ipapoda Olubadan ana, saaju ọjọ naa si ni gbogbo eeyan ilu ti mọ wi pe Ọba Raṣhidi Ladọja ni oye naa kan nitori ilana bi wọn ṣe n jẹ oye Olubadan ko ruju rara.
Ọjọ Ẹti, ọjọ Kẹjọ, oṣu Kẹjọ si ni eto isinku Ọba Olakulẹhin yoo waye nile ijọsin Saint Peter’s Cathedral, to n bẹ ni Aremo, Ibadan.
Ifakalẹ tó wáyé yii lati ọwọ igbimọ afọbajẹ ki wọn le mú orukọ ọhun ransẹ si ẹka ijọba to n risi ijọba ibilẹ ati oye jijẹ nipinlẹ Oyo.
Ladoja yoo di Olubadan ti ilẹ Ibadan kẹrinlelogoji, lẹyin ibuwọlu Gomina Seyi Makinde.
Ilana yiyan Olubadan ilẹ̀ Ibadan ko ruju rara, bẹẹ ni kii fa ariwo.
Koda, ẹni ti yoo jẹ Olubadan ni aimọye ọdun si asiko yii ti mọ ara rẹ lai jẹ pe akoko ti to.
Mogaji agboole ni awọn to wa lori ila jijẹ Olubadan ti ma n bẹrẹ si ni to.
Lẹyin naa ni yoo bẹrẹ si ni sun gẹgẹ bi ilana ọba jijẹ ni Ibadan titi de ipo Jagun Balogun – Ajia – Bada – Aare Onibon – Gbonnka – Aare Egbe Omo-Oota – Lagunna – Aare Ago – Ayingun – Asaju – Ikolaba – Aare Alasa – Agba Akin – Ekefa – Maye – Abese – Ekaarun Balogun – Ekeerin Balogun – Ashipa Balogun – Osi Balogun – Otun Balogun, Balogun, ko to wa di Olubadan ti ilẹ Ibadan.