Ìgbésẹ̀ ọ̀tun lórí bí America àti UAE ṣe mú kí físà gbígbà níra fún ọmọ Nàìjíríà
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ìjọba àpapọ̀ ti kéde ìfarajìn rẹ̀ láti rí i dájú pé, ìbáṣepọ̀ ọlọ́jọ̀ pípẹ́ tó wà láàárín Nàìjíríà àti ìjọba ilẹ̀ Amẹ́ríkà àti United Arab Emirates, UAE, ń gbòòrò si.
Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ Ààrẹ Bola Tinubu, Bayo Onanuga fi léde lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹẹ̀dógún, oṣù Keje, ọdún 2025 sọ pé ìjọba àpapọ̀ ti ń gbé ìgbésẹ̀ lórí àwọn ìròyìn tó ń jáde nípa àwọn àyípadà òfin táwọn orílẹ̀ èdè náà ń gbé jáde tako Nàìjíríà.
Onanuga ní, àwọn iléeṣẹ́ àti àjọ ìjọba àpapọ̀ tí ọ̀rọ̀ náà kàn ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ àti ìjíròrò láti wá ojútùú sáwọn nǹkan tó n kọ àwọn ọmọ Nàìjíríà lóminú lórí àwọn òfin náà.
Ó ṣàlàyé pé ìjọba Amẹ́ríkà ti fi àtẹ̀jáde síta pé nǹkan méjì gbòógì ló mú àwọn gbé ìgbésẹ̀ náà.
Àkọ́kọ́ ni pé orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà nílò láti ṣe àfọ̀mọ́ báwọn ọmọ Nàìjíríà ṣe máa ń lò kọjá ọjọ́ tí wọ́n bá fún wọn ní físà dà ní Amẹ́ríkà, tí wọ́n sì nílò àkọ́ọ́lẹ̀ tó péye nípa àwọn ọmọ Nàìjíríà tó wà ní ìlú wọn.
Bákan náà ló ní ìgbésẹ̀ náà wáyé látàrí àtúnṣe sí ètò gbígba físà èyí tí Amẹ́ríkà máa ń ṣe ní gbogbo ìgbà, tó sì jẹ́ pé wọ́n tún le ṣe àyípadà rẹ̀ láìpẹ́ tó fi mọ́ iye ìgbà tí èèyàn le wọ orílẹ̀ èdè náà pẹ̀lú físà kan.
Ó fi kun pé ààrẹ Bola Tinubu ti fèsì nípa dídarí gbogbo àwọn iléeṣẹ́ àtàwọn àjọ tí ọ̀rọ̀ kàn láti tẹ̀lé gbogbo àwọn ìlànà tó yẹ nípa níní àjọṣepọ̀ tó dán mọ́rán pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ òkèèrè àti níní àwọn àkọ́ọ́lẹ̀ tó yẹ nípa ẹnikẹ́ni tó bá ń gbèrò láti ṣe ìrìnàjò lọ sáwọn orílẹ̀ èdè mìíràn.
Ààrẹ tún rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti máa tẹ̀lé gbogbo òfin tó bá de físà wọn, kí wọ́n máa tẹ̀lé àwọn òfin tó rọ̀ mọ́ orílẹ̀ èdè tí wọ́n bá ṣàbẹ̀wò sí lójúnà àti ri pé wọn kò ba ọmọlúàbí wọn jẹ́ àti pé wọ́n jẹ́ kí àwọn míì rí àǹfàní bẹ́ẹ̀ jẹ.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìlànà tuntun tí UAE ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé jáde tako àwọn ọmọ Nàìjíríà, ìjọba àpapọ̀ ní àwọn aláṣẹ UAE kò ì tíì fi ohunkóhun ṣọwọ́ sáwọn nípasẹ̀ àtúnṣe tí wọ́n ṣe sí ìlànà físà gbígbà wọn.
Agbẹnusọ ààrẹ náà wòye pé ètò físà gbígbà ṣì ń lọ bó ṣe yẹ, tó sì ń lọ létòlétò.
Ó sọ pé ààrẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọba UAE pẹ̀lú àjọṣepọ̀ tó ń wáyé láàárín orílẹ̀ èdè méjéèjì àti pé gbogbo àwọn nǹkan táwọn èèyàn ń sọ lórí ìlànà tuntun yìí ni ìjọba ń gbé ìgbésẹ̀ lé lórí lọ́nà tó yẹ.
Ó sọ àrídájú rẹ̀ pé àwọn yóò ṣe àrídájú láti máa tẹ̀lé ìlànà tó yẹ láti mú ìgbé ayé rọrùn fáwọn èèyàn ní gbogbo ibi tí wọ́n bá fẹ́ gbé nílẹ̀ òkèèrè.
Ṣáájú ni ìjọba orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà kéde àtúnṣe sí bí àwọn èèyàn láti orílẹ̀ èdè míì ṣe le ṣàbẹ̀wò sí orílẹ̀ èdè náà tó fi mọ́ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Àtúnṣe sí ètò gbígba “físà” sí orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà yìí tí wọ́n pé ní ‘Visa Reciprocity Policy for Nigeria’ yóò bẹ̀rẹ̀ lójú ẹsẹ̀.
Ìgbésẹ̀ tuntun yìí máa ní ipa lórí àwọn tó bá ṣe àbẹ̀wò sí Amẹ́ríkà àmọ́ kò ní ní ipá lórí àwọn tó bá fẹ́ gba físà láti máa lọ gbé Amẹ́ríkà.
Èyí túmọ̀ sí pé láti àsìkò yìí, ọmọ Nàìjíríà tó bá fẹ́ gba físà láti lọ ṣàbẹ̀wò sí Amẹ́ríkà kò ní ní àǹfàní láti wọ orílẹ̀ èdè náà ju ẹ̀ẹ̀kan péré lọ àti pé wọn kò ní ní àǹfàní láti lo ju oṣù mẹ́ta lọ.
Ṣáájú àsìkò yìí, Amẹ́ríkà máa ń fún àwọn ọmọ Nàìjíríà ní físà láti ṣàbẹ̀wò sí orílẹ̀ èdè náà fún bíi ọdún méjì sí márùn-ún.
Láàárín ọdún náà, èèyàn le wọ Amẹ́ríkà kò sí jáde ní iye ìgbà tó bá wù ú títí tí ọjọ́ fi máa lọ lórí físà náà ṣùgbọ́n èyí ti yípadà báyìí.
Àtẹ̀jáde kan tí iléeṣẹ́ Amẹ́ríkà ní Nàìjíríà fi sójú òpó ìtàkùn ayélujára wọn lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun sọ pé gbogbo àwọn tó ti àwọn ti fún ní físà ṣáájú ọjọ́ Kẹjọ, oṣù Keje ló máa wà bó ṣe wà, tí wọ́n sì máa lo ìgbà tí wọ́n fún wọn pé.
Àtẹ̀jáde náà ṣàlàyé pé ìgbésẹ̀ yìí ń wáyé nítorí pé ó pọn dandan láti máa ṣe àtúnṣe sí ètò ìrìnnà wọn ní gbogbo ìgbà.
Wọn fi kun pé ìgbésẹ̀ náà tún ń wáyé láti gbẹ̀san ètò físà gbígbà táwọn orílẹ̀ èdè mìíràn ń gbé kalẹ̀ fún wọn tó fi mọ́ Nàìjíríà.
Lẹ́yìn tí Amẹ́ríkà kéde ìpinnu rẹ̀ yìí náà ni United Arab Emirates náà gbé òfin síta nípa ìlànà gbígba físà fáwọn ọmọ Nàìjíríà.
Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde tí Amẹ́ríkà gbé kalẹ̀, wọ́n ní ìlànà mẹ́ta ni ìjọba Nàìjíríà gbọ́dọ̀ tẹ̀lé kí ètò gbígba físà lè máa lọ bó ṣe yẹ.
Níní àwọn ìwé ìrìnnà tó péye lọ́wọ́: wọ́n ní àwọn orílẹ̀ èdè tó ń wọ Amẹ́ríkà gbọdọ̀ ṣe àrídájú rẹ̀ pé wọ́n ní àkọ́ọ́lẹ̀ àti àmì ìdánimọ̀ àwọn èèyàn tó péye lọ́wọ́.
Ṣíṣe àtúnṣe sí báwọn èèyàn ṣe ń kọjá ìgbà tí wọ́n fún wọn: Wọ́n gbọ́dọ̀ gbé ìgbésẹ̀ láti ri pé àwọn tó ń wọ Amẹ́ríkà kò máa lò ju gbèdéke àsìkò tí wọ́n fún wọn lọ.
Gbígbé ìmọ̀ nípa ẹni tó ń gba físà jáde: wọ́n ní wọn gbọdọ̀ máa pèsè àwọn ìròyìn tó yẹ, yálà nípa àwọn ìwà ọ̀daràn tí ẹni tó bèèrè bá ti wù sẹ́yìn láti dá ààbò bo àwọn aráàlú.
Wọ́n fi kun pé àwọn ní ìfarajìn sí ìbáṣepọ̀ tó wà láàárín orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà àti Nàìjíríà láti ọjọ́ pípẹ́ lójúnà àti mú kí orílẹ̀ èdè méjéèjì wà ní ààbò tó péye.
Àtẹ̀jáde wá kan sáárá sí àjọ tó ń rí sí ètò ìwọléjáde èrò èrò ní Nàìjíríà àtàwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò fún iṣẹ́ takuntakun wọn láti ri pé wọ́n ṣàmúlò ìlànà tó yẹ.
Bákan náà ni wọ́n rọ àwọn arìnrìnàjò ní Nàìjíríà láti rip é wọ́n ń tẹ̀lé ohun tí físà wọn bá sọ, kí wọ́n sì ri pé àwọn ìwé ẹ̀rí tí wọ́n fi ń ṣe ìrìnàjò pé pérépéré, kí wọ́n sì ri pé ó jẹ́ ojúlówó.