Buhari wọ káà ilẹ̀ sùn, àwọn ológun àti èèkàn ìlú ṣe ẹyẹ̀ ìkẹyìn fún un
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwáyé è kú kò sì ,ẹ̀dáó má fikú yọ ẹ̀dá ẹgbẹ́ rẹ̀, gbogbo wa ni a jẹ gbèsè ikú,ìgbà àti àsìkò ló sàrà ọ̀tọ̀
Ìbànújẹ́ bá gbogbo ọmọ ìlú Daura ní ìpínlẹ̀ Katsina nígbà tí wọ́n gbé ọmọ wọn, Muhammadu Buhari, ẹni tó ti fi ìgbà kan jẹ Ààrẹ ológun àti Àárẹ̀ tí a dìbò yàn lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, wọ ìlú náà
Ki I ṣe igba akọkọ ree ti Buhari yoo wa si ilu rẹ ṣugbọn lasiko yii, wọn gbe wọle lai si ẹmi lara.
Ni dede aago mẹfa ku isẹju marun un ni wọn gbe Aarẹ ana, ẹni ọdun mejilelọgọrin wọ kaa ilẹ niwaju awọn iyawo, ọmọ, mọlẹbi, ara ati ọrẹ, pe o di gba.
Aarẹ Buhari lo ọdun mẹsan an ati oṣu mẹjọ ni ijọba, eyi to jẹ apapọ ọdun to fi tukọ orilẹede Naijiria, gẹgẹ bii ologun ati aarẹ ti a dibo yan, eyi to sọ di olori to pẹ ju ninu itan orilẹede Naijiria
Ọpọ awọn eeyan lo peju sibi eto isinku, lara wọn ni ati ri iyawo oloogbe, Aisha Buhari, Aarẹ orilẹede Naijiria, Aarẹ Bola Tinubu; igbekeji rẹ, Kashim Shettima; igbekeji Buhari fun ọdun mẹjọ, Yemi Osinbajo; igbakeji aarẹ nigba kan ri Atiku Abubakar; oniṣowo, Aliko Dangote; awọn gomina ati gomina tẹlẹ, minisita, lọbalọba, olori ẹṣin ati awon mii.
Saaju eto isinku, Tinubu tẹwọgba oku aarẹ ana ni paapa ofurufu Katsina kete to de lati ilu London