Wọ́n ti dá iléeṣẹ́ Trump, Ààrẹ Amẹ́ríkà tẹ́lẹ̀ lẹ́bi ìwà ọ̀daràn owó orí

Wọ́n ti dá iléeṣẹ́ Trump, Ààrẹ Amẹ́ríkà tẹ́lẹ̀ lẹ́bi ìwà ọ̀daràn owó orí

Ọrẹ Òtítọ́jù

À ṣé kò síbi téṣe kò sí, ìgbìmọ̀ ìdájọ́ kan ní New York lórílẹ̀èdè Amẹ́ríkà ti dá ẹ̀bi fún iléeṣẹ́ ìdílé Ààrẹ tẹ́lẹ̀ nílẹ̀ Amẹ́ríkà, Donal Trump lórí ìwà ọ̀daràn tó rọ̀ mọ́ owó orí.

Wọn da ileeṣẹ Trump Organisation lẹjọ lori gbogbo ẹsun ti wọn fi kan an lọjọ Iṣẹgun lẹyin ọjọ meji ti wọn fi jiroro lori ọrọ naa ni New York.

Ileeṣẹ naa sun mọ aarẹ ana lorilẹede Amẹrika naa atawọn mọlẹbi rẹ amọ awọn mọlẹbi rẹ kọ ni wọn pe lẹjọ.

Wọn da ileeṣẹ Aarẹ Donald Trump lẹbi pe o n da awọn alaṣẹ rẹ lọla pẹlu awọn ọla ti ko si ninu akọsilẹ fun bi ọdun mẹwaa.

Lara awọn dukia ti wọn fun awọn adari ileeṣẹ naa lai san owo ori lori wọn ni ọkọ ayọkẹlẹ ati owo ilẹ iwe aladani.

Awọn olupẹjọ ni eyi mu ki owo oṣu wọn ati owo ori to tọ si wọn lati san wa kere pupọ.

Faini miliọnu kan ati ẹgbẹta dọla lo ṣeeṣe ki wọn koju. O si tun ṣeeṣe ki ipenija wa fun wọn lọjọ iwaju lati ya owo.

Aarẹ Trump bu ẹnu atẹ lu igbẹjọ naa leyi to ni o lọwọ oṣelu ninu.

Bakan naa lo tunkoju oro si alamojuto iṣuna ileeṣẹ rẹ fun ọjọ pipẹ, Allen Weisselberg, o fi ẹsun kan an pe o lu jibiti owo ori.

Awọn olupẹjọ fi ẹsun kan ileeṣẹ aarẹ Trump naa pe “iwa itanjẹ ati jibiti ti di mọọliki mọ wọn lara”

Awọn olupẹjọ ni ile iṣẹ naa mu ki awọn adari rẹ o lanfani ati ‘din iye owo ti wọn n kede pe awọn n gba ku ki owo ori ti wọn n san lee kere.”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here