Asẹ́wó kú s’ọ́wọ́ ènìyàn mẹ́ta l’Ondo

Asẹ́wó kú s’ọ́wọ́ ènìyàn mẹ́ta l’Ondo

Yínká Àlàbí

Ọga ọlọpaa DSP Oluṣọla Ayanlade salaye yii ni ilu Akure ni ana ọjọ Aje pe ọwọ sinkun ofin ti tẹ awọn eniyan mẹta ni ile itura Brothel to wa ni agbegbe Cathedral ni Akure. Arakunrin kan lo gbe alasewo kan lọ si ile itura. Nigba to di ki ere bẹrẹ ni arabinrin naa ni ara oun ko ya daadaa ati wi pe oun ko ni le se isẹ naa mọ.
Wọn bẹrẹ ariyanjiyan gidi lori ọrọ yii ni eyi to mu ki wọn ko ara wọn jade sita ti manega ilu itura naa gbiyanju lati ba wọn pari rẹ. Arakunrin to gbee lọ si ile itura ni ko si ija ki alasewo naa ba oun mu ẹgbẹrun meedogun ti oun fun un f’owo isẹ, alasewo naa kọ jale pe oun ko ni ko owo naa silẹ.
Ibi ariwo naa ti ọkunrin to ni owo ti pe awọn eniyan rẹ pe obinrin kan fẹ yan oun jẹ. Bi awọn naa se da debẹ mu ki ẹru ba awọn to ni ile itura, wọn si sare pe agọ ọlọpaa. Ọwọ awọn ọlọpaa tẹ mẹta ninu awọn ọkunrin naa, wọn si sare gbe alasewo naa lọ si ile iwosan awọn ọlọpaa to wa ni Akure.
Ile iwosan naa ni wọn ti salaye fun awọn ọlọpaa pe obinrin naa ti jẹ ipe Ọlọrun ko to de ile iwosan. Wọn ti tẹ obinrin naa si aaye igboku si ni ile iwosan fun ayẹwo to daju.
Iwadii si n tẹ siwaju ni ko jẹ ki Ọga ọlọpaa Ayanlade darukọ awọn ti ọrọ naa kan.