Ọwọ́ tẹ olóyè tó jí ọmọdébìnrin kan gbé ní ìpínlẹ̀ Ondo
Mary Fágbohùn
Oloye kan niluu Laaagba ni ijọba ibilẹ ila oorun Ondo, Adeniyi Ifedayo, ni awon ọlọpaa ti mu won si ti fi si atimọle lori ẹsun pe o ji ọmọdebinrin ọdun mejila gbe ti o si tun fipa ba a lopọ.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Olayinka Ayanlade, lo fidi ọrọ yii mulẹ fun awon oniroyin.
Iroyin jabo pe Oloye Ifedayo ọhun tan ọmọbinrin naa wọ ile rẹ, nibi ti o ti i mọ fun ọsẹ meji to si n fipa ba ọmọde naa lopọ.
Ẹnikan to n gbe ni agbegbe ti iṣẹlẹ ọhun ti wáyé, sọ fawọn akọroyin wi pe afurasi ọlọkada kan lo gbe ọmọ naa lọ si ile oloye naa.
Ẹni to wa lagbegbe ti iṣẹlẹ ọhun ti waye fikun ọrọ rẹ pé, ẹkọ ni Oloye naa n fun ọmọbinrin ọhun mu lojoojumọ, ti o si n tun fipa ba a lopọ.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, Agbẹnusọ fún ileeṣẹ ọlọpaa Ondo, Olayinka Ayanlade sọ pe afurasi ọlọkada to ṣiṣẹ pọ pẹlu Oloye Ifedayo ti sá lọ.
O fi kun un pé ileeṣẹ ọlọpaa si n wa ọlọkada yii.
”Awa ọlọpaa n sa gbogbo agbara ati ipa wa lati mu afurasi to ṣiṣẹ pọ pẹlu oloye naa.
Oloye Ifedayo ti wa ni atimọle ọlọpaa bayii, a n gbiyanju lati wa gbogbo ẹri lori iṣẹlẹ naa.
Iwadii si n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa, afurasi oloye yii yoo foju ba ile ẹjọ lẹyin ti a ba ti pari iwadii ti a n ṣe lori iṣẹlẹ naa.
Afurasi ọlọkada to gbimọ pọ pẹlu Oloye Ifedayo naa yoo foju ba ile ẹjọ ti ọwọ ba ti tẹ ẹ.
Ọrọ naa ti de olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo bayii fun iwadii to munadoko lori iṣẹlẹ naa,” Ayanlade lo sọ bẹẹ.