Ìjo̩ba ìbílè̩ Onigbongbo l’Ekoo sì ń dá bírà

Ìjo̩ba ìbílè̩ Onigbongbo l’Ekoo sì ń dá bírà

Yínká Àlàbí

Idagbasoke ojoojumo̩ to n ba Onigbongbo lo je̩ ki ileese̩ iwe IROYIN OWURO̩ te̩ o̩ko̩ leti lati je̩ ipe
Alaga Ijo̩ba ibile̩ naa. Ijo̩ba ibile̩ Onigbongbo wa ni ipinle̩ Eko. Gbogbo awo̩n adugbo bii O̩pe̩bi, Allen, O̩re̩gun, to fi de Maryland ati be̩e̩ be̩e̩ lo̩ ni wo̩n wa labe̩ isejo̩ba Onigbongbo. Hon.Barr. Rekiya Hassan tun fi n da gbogbo oniroyin loju pe keesekese ni wo̩n tii ri, kaasakasa n bo̩ lo̩na, kaasakasa ti se baba keesekeese. O ni awo̩n ara adugbo Onigbongbo si maa gbadun isejo̩ba oun ju bayii lo ti e̩gbe̩ APC ba le jawe olubori ninu idibo ijo̩ba ibile̩ to n bo̩ lo̩na. Barr Rekiya ni o wu oun lati maa se akanse ise̩ lojoojumọ ju oni oso̩o̩se̩ ti isejo̩ba awo̩n n se yii lo̩.
O̩s̩e̩ to ko̩ja ni a jo̩ si awo̩n akanse bii opopona lorisiirisii pe̩lu ago̩ o̩lo̩paa igbalode ni O̩re̩gun ni eyi to gbe ko̩miso̩na o̩lo̩paa O̩gbe̩ni Olohundare Mo̩shood Jimo̩h gan-an dide.
Bi ojumo̩ toni tun ti mo̩ ni a tun ti be̩re̩ si ni si awo̩n opopona ti ijo̩ba naa se bii Tiwalade close, Ibadan close ati Adedeji close ti awo̩n me̩te̩e̩ta wa ni Ilu O̩pe̩bi. Le̩yin eyi ni a tun te̩ siwaju lati lo̩ si Aderibigbe street, Wasimi pelu 114 Road (Wasimi peace estate) ni Maryland kan naa.
Akiyesi awo̩n ara ilu ni pe ti gbogbo awo̩n oloselu ba le maa sise̩ bii Hon. Barr. Rekiya Hassan, ko ni si o̩na ti ko dara mo̩ ni orileede yii.
Adura awo̩n ara ilu ijo̩ba ibile̩ Onigbongbo ni pe ki Alaga naa wo̩le, ki Eledua ma si je̩ ki o dawo̩ oore re̩ duro.
Omowe Sogbehin Abdulganiyu Oluremi to je̩ ogunna gbongbo ninu olori e̩gbe̩ oselu APC ni ilu naa ni, ko gbo̩do̩ ma ri be̩e̩ nitori pe e̩gbe̩ oselu awo̩n maa n ni afojusun ni ilu tabi ipinle̩ ti wo̩n ba ti ba ara wo̩n. Alagba yii ni gbogbo atile̩yin ni awo̩n n fun Alaga lati ma se je̩ ki o kuna tabi ki awo̩n eniyan kan ma lo̩ maa so̩ pe nitori pe o je̩ obinrin ni ko je̩ ki o ri ojutuu isejo̩ba naa.