Ọbásanjọ́ kò buwọ́lu $6bn láti kọ́ ibùdó amúnáwá Mambilla – Ẹlẹ́rìí
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ẹlẹ́rìí kan ti sọ fún ilé ẹjọ́ gíga nílùú Àbújá wí pé Ààrẹ orilẹ́èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ , Olóyè Olusegun Obasanjo kò buwọ́lu $6bn tí ẹjọ́ ń lọ lórí rẹ̀ fún ilé iṣẹ́ Sunrise Power láti kọ́ ilé iṣẹ́ amúnáwá Mambilla.
Nigba to n jẹrii niwaju adajọ Jude Onwuegbuzie niluu Abuja, Umar Babangida to jẹ oluwadii pẹlu ajọ EFCC ṣalaye pe, eyi wa ninu iwe akọsilẹ ti Obasanjo fi ransẹ si EFCC pe oun ko buwọlu iṣẹ akanṣe kikọ ibudo amunawa ọhun eyiti Minisita tẹlẹ fun ohun amuṣagbara ati irin tutu ilẹ wa, Olu Agunloye, gbe fun ileeṣẹ Sunrise Power.
Ti ẹ o ba gbagbe, EFCC n ṣe ẹjọ pẹlu Agunloye lori ẹsun onikoko meje to da lori yiyi iwe, titapa si ọrọ aarẹ ati fifun eeyan ni owo ẹyin.
EFCC fẹsun kan Agunloye pe o gbe akanṣe iṣẹ ileeṣẹ amunawa Mambilla fun ileeṣẹ Sunrise Power lọjọ kejilelogun oṣu Karun un ọdun 2003 lai gbaṣẹ lọwọ aarẹ ati lai si ninu eto iṣuna.
Ajọ naa tun sọ pe minisita tẹlẹ ri ọhun tẹwọ gba N5.212m lọwọ ileeṣẹ Sunrise Power & Company Limited (SPTCL) ati lọwọ Ọgbẹni Leno Adesanya nipasẹ Ọgbẹni Jide Abiodun Sotinrin.
Ajọ EFCC fikun ọrọ rẹ pe akaunti banki GTB Agunloye ni wọn ṣe owo naa si fun un eyi to wa fun imọriri akitiyan rẹ lori bi o ti gba iyọnda ijọba fun ileeṣẹ SPTCL lati kọ ileeṣẹ amunawa Mambilla.
Amọ, minisita tẹlẹri naa ti sọ pe oun ko jẹbi gbogbo ẹsun ti wọn fi kan oun.
Ṣugbọn Ọgbẹni Babangida to jẹ ẹlẹrii sọ fun ile ẹjọ wi pe ‘Oloye Obasanjo to dari ipade igbimọ alaṣẹ ijọba lọjọ kọkanlelogun oṣu Karun un ọdun 2003 kọ lẹta si agbẹjọro agba Naijiria lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kọkanla ọdun 2023 wi pe oun ko buwọlu iṣẹ akanṣe kankan fun ileeṣẹ Sunrise Power.
Obasanjo ni oun kan sọ fun minisita pe ko gbe ọrọ naa kalẹ lasiko ipade igbimọ alaṣẹ ni ati pe igbimọ alaṣẹ pada sọ fun minisita wi pe ko si duro na lori akanṣẹ iṣẹ ọhun.”
Alukoro ajọ EFCC, Dele Oyewale, ṣalaye lọjọ Aje wi pe Ọgbẹni Babangida tun sọ pe Obasanjo loun kọ loun buwọlu lẹta akanṣe iṣẹ naa ti Agunloye gbe jade lọjọ kejilelogun oṣu Karun un ọdun 2003.
O ni bakan naa ni Obasanjo tun sọ pe kii ṣe igbimọ alaṣẹ ijọba lo buwọlu lẹta naa pẹlu.
Ẹlẹrii tun sọ fun ile ẹjọ wi pe bo tilẹ jẹ pe ijọba apapọ ni ki oriṣiiriṣii ileeṣẹ kọ iwe si ijọba pe awọn le ṣe akanṣe iṣẹ ileeṣẹ amunawa Mambilla, o ni laarin ọjọ kan ṣoṣo ni Agunloye gbe iṣẹ naa fun ileeṣẹ Sunrise Power.
”Nnkan ti ijọba apapọ sọ fun minisita ni pe ko ranṣẹ pe awọn olokowo sii to le ṣiṣẹ ileeṣẹ amunawa Mambilla naa.
Amọ, lọjọ kejilelogun oṣu Karun un ọdun 2003 ti i ṣe ọjọ keji ipade igbimọ alaṣẹ ni minisita gbe iṣẹ naa fun ileeṣẹ Sunrise Power,” Babangida lo sọ bẹẹ.
Babangida tun sọ fun ile ẹjọ wi pe iwadii EFCC fi han pe ileeṣẹ Sunrise Power san awọn owo kan fun Agunloye.
Babangida sọ pe ”iwadii fi han pe olujẹjọ gba N3.6m lọjọ kẹwaa oṣu Kẹjọ ọdun 2019.
O tun gba N500,000 lọjọ kejilelogun oṣu Kẹwaa ọdun 2019, bakan naa lo tun gba N1.1m lọjo kẹtala oṣu Kọkanla ọdun 2019 bakan naa.
Shotire Jide Abiodun, to jẹ amugbalẹgbẹ Leno Adesanya to ni ileeṣẹ Sunrise Power lo san gbogbo owo yii fun Ọgbẹni Agunloye.”
Igbẹjọ tẹsiwaju nile ẹjọ giga niluu Abuja .